“Títukọ̀ Nígbà Tí Ìjì Líle Ń Jà”
ǸJẸ́ o kò ní ka irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ìfàkókòṣòfò, ìwà òmùgọ̀, àti ìgbésẹ̀ tó lè fa jàǹbá? Àmọ́ ṣá o, lọ́nà àpèjúwe, àwọn kan ń fi ara wọn sírú ipò bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo? Òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, Thomas Fuller, wí pé: “Má ṣe fi inú fùfù ṣe ohunkóhun. Bí títukọ̀ nígbà tí ìjì líle ń jà ló rí.”
Béèyàn bá gbé ìgbésẹ̀ kan nígbà tí kò lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀, ó lè yọrí sí ohun búburú. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì jẹ́rìí sí èyí. Síméónì àti Léfì, àwọn ọmọ Jékọ́bù, baba ńlá ìgbàanì, hùwà padà sí títẹ́ tí a tẹ́ arábìnrin wọn, Dínà, lógo, wọ́n fara ya láti lè fìbínú gbẹ̀san. Ìpànìyàn rẹpẹtẹ àti pípiyẹ́ ló yọrí sí. Abájọ tí Jékọ́bù kò fi fara mọ́ ìwà burúkú wọn, tó fi sọ pé: “Ẹ ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí mi ní sísọ mí di òórùn burúkú lójú àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí.”—Jẹ́nẹ́sísì 34:25-30.
Ó bọ́gbọ́n mu pé, òdìkejì ìwà yìí ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbani nímọ̀ràn. Ó sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yẹn lè dènà ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.—Oníwàásù 10:4; tún wo Òwe 22:24, 25.