ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/15 ojú ìwé 32
  • Ìwà Ipá—Láìpẹ́ Yóò Dópin Títí Láé!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Ipá—Láìpẹ́ Yóò Dópin Títí Láé!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/15 ojú ìwé 32

Ìwà Ipá—Láìpẹ́ Yóò Dópin Títí Láé!

“Ìwà Ipá Ń Wu Orílẹ̀ Èdè Kan Léwu”—The New York Times, láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

“Ìwà Ipá Nínú Ilé”—O Globo, láti ilẹ̀ Brazil.

“Ìwà Ipá Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣe Àwọn Obìnrin Lọ́ṣẹ́ Kárí Ayé”—The Globe and Mail, láti Kánádà.

ÀKỌLÉ gàdàgbà wọ̀nyí láti inú àwọn ìwé ìròyìn táa ń tẹ̀ jáde ní Ilẹ̀ Àríwá àti Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa nǹkan kan tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ ọ́ láìpẹ́ yìí, “gbogbo onírúurú ìwà ipá ló ti búrẹ́kẹ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.”

Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ tó ń dótùútù múni yìí:

Ìpànìyàn. Ní ilẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà àti Caribbean, nǹkan bí àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà [1,250] ló ń ṣalábàápàdé ikú lójoojúmọ́ látàrí ìwà ipá. Èyí ló fi jẹ́ pé, “nínú ìlàjì àwọn orílẹ̀ èdè tó wà ní àgbègbè yẹn, ìpànìyàn ló gba ipò kejì nínú ohun tí ń ṣekú pa àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélógún.”

Ìwà ipá sí àwọn ọmọdé. Lílu ọmọdé nílùkulù, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, àti kíkó ìdààmú ọpọlọ bá wọn, jẹ́ àwọn ìṣòro tó kárí ayé. Fún àpẹẹrẹ, “àwọn àgbà kan táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè onímọ̀ ẹ̀rọ fi hàn pé ìpín mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé ni a ti bá ṣèṣekúṣe—ọ̀dọ́bìnrin sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn.”

Ìwà ipá sí àwọn obìnrin. Lẹ́yìn ṣíṣèwádìí nípa títẹ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú kárí ayé lọ́dún 1997, àwọn olùwádìí parí èrò sí pé “ìwà ipá nínú ilé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdí pàtàkì táwọn obìnrin fi máa ń fara gbọgbẹ́ ní gbogbo orílẹ̀ èdè ayé.” (Human Rights Watch World Report 1998) Ìwà ipá nínú ilé, tó tàn kálẹ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ, ṣùgbọ́n tí a kì í sábàá sọ síta, ni ìṣòro táa wá ń pè ní “rògbòdìyàn mẹ́numọ́ báyìí ní ọ̀rúndún ogún yìí.”—The Globe and Mail, láti ilẹ̀ Kánádà.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ilé ayé “kún fún ìwà ipá” láyé Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9-12) Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run dáàbò bo “oníwàásù òdodo” yẹn àti ìdílé rẹ̀ “nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Ọlọ́run yóò gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ wa. Òun yóò pa “àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sìn [ín]” mọ́, nígbà tó bá mú àwọn oníwà ipá àti àwọn olubi kúrò, tó bá sì sọ ayé yìí di párádísè nínú ayé tuntun tó ti ṣèlérí. (2 Pétérù 2:4-9; 3:11-13) Ǹjẹ́ inú rẹ kò dùn láti mọ̀ pé láìpẹ́ ìwà ipá yóò dópin títí láé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́