Máà Ba Orúkọ Rere Rẹ Jẹ́
WÍWO àwòrán mèremère kan fínnífínní mà máa ń gbádùn mọ́ni o. Bí o bá wò ó láwòfín, o lè rí bí ayàwòrán kan ṣe lo búrọ́ọ̀ṣì rẹ̀ láìmọye ìgbà láti fi onírúurú àwọ̀ kun iṣẹ́ ọ̀nà náà.
Bákan náà, èèyàn kì í ṣàdédé ní orúkọ réré, kí a sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, kì í ṣe bí ẹni gbé ọwọ́ búrọ́ọ̀ṣì ńlá lé àwòrán kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè ní in nípa híhùwà rere fún ìgbà pípẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, díẹ̀díẹ̀ la máa ń mú orúkọ rere dàgbà nípa àwọn ìwà rere tí à ń hù.
Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, táa bá ṣi ọwọ́ búrọ́ọ̀ṣì kan gbé, ó lè ba àwòrán náà jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni orúkọ wa. Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì wí pé: “Ìwà òmùgọ̀ ará ayé ni ó lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po.” (Òwe 19:3) Ìwà òmùgọ̀ díẹ̀—bí inúfùfù, fífi ọtí kẹ́ra ẹni bà jẹ́, tàbí ìwà àìmọ́ takọtabo ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo—ló ń ba orúkọ rere èèyàn jẹ́. (Òwe 6:32; 14:17; 20:1) Nítorí náà, ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó fún wa láti gbìyànjú pé a ní orúkọ rere, kí a sì fi taratara ṣiṣẹ́ láti má ṣe bà á jẹ́.—Fi wé Ìṣípayá 3:5.