Ní Ọgbọ́n Láti “Mọ Ohun Tí Yóò Ṣẹlẹ̀”
“ÀWỌN èèyàn tí kò ní agbára ìmòye rere, tí kò sì lóye ni wọ́n. Bí wọ́n bá gbọ́n, wọn óò lóye èyí wọn óò sì mọ ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.”—Diutarónómì 32:28, 29, Beck.
Mósè ló sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní bèbè àtiwọ Ilẹ̀ Ìlérí. Mósè ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí wọn yóò kọ Jèhófà sílẹ̀, tí wọn kò sì ní fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí ohun tí yóò jẹ́ àbájáde ìwà wọn. Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì—títí kan ọ̀pọ̀ ọba—gbójú fo àwọn ìkìlọ̀ Ọlọ́run dá.
Fún àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì mọ àṣẹ Ọlọ́run láti má ṣe fi àwọn tí ń sin àwọn ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Jèhófà ṣaya. (Diutarónómì 7:1-4) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya ilẹ̀ òkèèrè.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń darúgbó lọ pé àwọn aya rẹ̀ alára ti tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn; ọkàn-àyà rẹ̀ kò sì pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Ọba 11:1, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n ní Sólómọ́nì, kò ní agbára ìmòye rere láti ‘mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀’ bí òun bá ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run.
Àwa náà ńkọ́? A lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìrora bí a ba ronú jinlẹ̀ dáadáa kí a tó ṣe àwọn ìpinnu tó kan ìgbésí ayé wa. Fún àpẹẹrẹ, a gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn láti “wẹ ara [wọn] mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Èyí bọ́gbọ́n mu, àmọ́, ọ̀pọ̀ ni kò ní agbára ìmòye rere láti mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí wọn kò bá ka ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fúnni sí. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń ba ara wọn jẹ́ nípa tábà mímu, tí wọ́n ń rò pé ìyẹn yóò sọ wọ́n di ẹni tó lajú, tó sì tójúúbọ́. Ẹ wo bí àbájáde rẹ̀ ṣe máa ń bani nínú jẹ́ tó, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn kan lára wọn yóò wá di ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ kò lè ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, tí àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró kò jẹ́ ó gbádùn, tàbí tí ara rẹ̀ wá wú rọ́tọ́rọ́tọ́!
Ó ṣe pàtàkì kí a gbé àbájáde àwọn ìpinnu wa àti ìṣe wa yẹ̀ wò dáadáa. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú; nítorí ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹran ara rẹ̀ lọ́kàn yóò ká ìdíbàjẹ́ láti inú ẹran ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí.”—Gálátíà 6:7, 8.