Ìmọ̀ràn Lórí Yíyan Ọ̀rẹ́ Rere
ÌRÒYÌN tó jáde nínú ìwé ìròyìn Reader’s Digest sọ pé, àwọn èwe sábà máa ń yíjú sí àwọn ojúgbà wọn fún ìmọ̀ràn lórí ìwọṣọ àti orin ju àwọn òbí wọn lọ. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí mọ irú ẹgbẹ́ táwọn ọmọ wọn ń kó àti ibi tí wọ́n ń ṣeré lọ.
Esmé van Rensburg, olùkọ́ àgbà ní ẹ̀ka ìfìṣemọ̀rònú ní yunifásítì kan ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé, “Ojúṣe yín ni láti ṣèwádìí.” Ó fi kún un pé: “Ó ṣeé ṣe pé káwọn ọmọ rẹ kọ́kọ́ bínú, ṣùgbọ́n ìbínú wọn á tún rọlẹ̀.” Lẹ́yìn náà ló wá sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí táwọn òbí lè ṣe. Àṣẹ tẹ́ẹ bá pa gbọ́dọ̀ bọ́gbọ́n mu, ó sì gbọ́dọ̀ ní àwọn ìlànà kan tó kín in lẹ́yìn; máa fetí sílẹ̀ sáwọn ọmọ rẹ; má ṣe jẹ́ kára rẹ gbóná jù bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ fara balẹ̀, kóo sì mọ ohun tóo fẹ́ sọ. Bó bá jẹ́ pé ọmọ rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn èèyànkéèyàn kan rìn, jẹ́ kó mọ ìwà àìdáa tí irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ ti mú kó máa hù, kì í kàn ṣe pé kóo ní kó má bá wọn rìn mọ́.
Ìmọ̀ràn tó yè kooro tó wà fáwọn òbí ti wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí í ṣe Bíbélì, tipẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Ìwé Mímọ́ tún fúnni ní ìmọ̀ràn rere yìí lórí báa ṣe lè yan ọ̀rẹ́ tó dára, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Owe 13:20) Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ ọgbọ́n tó wà fún àwọn tó bá ń fi ìmọrírì ka Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ohun tó sọ sílò nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́.