Ṣíṣàlàyé Bíbélì—Ta Ló Ń Darí Rẹ̀?
Ọ̀KAN lára ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ṣàlàyé,” ni “kí ẹnì kan fi ohun tó gbà gbọ́, èrò rẹ̀, tàbí ipò rẹ̀ sọ bó ṣe lóye ohun kan sí.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Nípa báyìí, ipò àtilẹ̀wá, ìmọ̀ ẹ̀kọ́, àti báa ṣe tọ́ ẹnì kan dàgbà, máa ń nípa lórí bí onítọ̀hún yóò ṣe ṣàlàyé ohunkóhun.
Àlàyé Bíbélì wá ńkọ́ o? Ǹjẹ́ a lómìnira láti ṣàlàyé Bíbélì ní ìbámu pẹ̀lú “èrò, ìgbàgbọ́, tàbí ipò” wa? Bó ṣe sábà máa ń rí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn atúmọ̀ èdè ló máa ń sọ pé àwọn kò ṣàdédé ṣe ohun táwọn ṣe, wọ́n máa ń sọ pé, Ọlọ́run ló darí àwọn.
Àpẹẹrẹ kan ni ti àlàyé tí wọ́n ṣe sí ìsàlẹ̀ ìwé Jòhánù 1:1 nínú Bíbélì A New Version of the Four Gospels, tí John Lingard tẹ̀ jáde lọ́dún 1836, lábẹ́ orúkọ awúrúju náà “Kátólíìkì.” Ó wí pé: “Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ló ń sọ pé ẹ̀rí ohun tí àwọn gbà gbọ́ ń bẹ nínú Ìwé Mímọ́: àmọ́, ká sòótọ́, kì í ṣe Ìwé Mímọ́ ló fi yé wọn bẹ́ẹ̀, àwọn fúnra wọn ló gbé ìtumọ̀ tiwọn wọnú ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a fara mọ́ kókó náà, kí lèrò òǹkọ̀wé náà? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ìtumọ̀ ẹsẹ náà lẹ́yìn, èyí tó túmọ̀ báyìí: “Ní àtètèkọ́ṣe ni ‘ọ̀rọ̀’ wà; ‘ọ̀rọ̀ náà’ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run; ‘ọ̀rọ̀ náà’ sì jẹ́ Ọlọ́run,” àpẹẹrẹ ìtumọ̀ kan nìyí tó ti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn.
Kí ló sún òǹkọ̀wé náà láti fi ìtumọ̀ Jòhánù 1:1 ti ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn? Ṣé “Ìwé Mímọ́ ló ní” kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Ìyẹn ò lè rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti fi ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kọ́ni. Ṣàkíyèsí ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ nípa kókó yìí pé: “Yálà ọ̀rọ̀ náà Mẹ́talọ́kan tàbí àlàyé ẹ̀kọ́ náà, kò séyìí tó fara hàn nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Ní àfikún sí i, ọ̀jọ̀gbọ́n E. Washburn Hopkins ti Yunifásítì Yale, sọ pé: “Jésù àti Pọ́ọ̀lù kò mọ ohun tí ń jẹ́ ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan rárá; . . . wọn kò sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.”
Nígbà náà, kí la lè sọ nípa àwọn tí wọ́n ti ìtumọ̀ Mẹ́talọ́kan tó wà nínú Jòhánù 1:1 tàbí ẹsẹ Bíbélì mìíràn lẹ́yìn? Táa bá gbé e ka ọ̀pá ìdiwọ̀n ti Ọ̀gbẹ́ni Lingard, “kì í ṣe Ìwé Mímọ́ ló fi yé wọn bẹ́ẹ̀, àwọn fúnra wọn ni wọ́n gbé ìtumọ̀ tiwọn wọnú Ìwé Mímọ́.”
A dúpẹ́ pé, a ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti darí wa nípa èyí. Àpọ́sítélì Pétérù wí pé: “Ẹ mọ èyí lákọ̀ọ́kọ́ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tí ó jáde wá láti inú ìtumọ̀ ti ara ẹni èyíkéyìí. Nítorí a kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”—2 Pétérù 1:20, 21.