Ẹ̀mí Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti Ìsìn
“NÍGBÀ tí ìwé ìròyìn Time fọ̀rọ̀ wá Mark Mathabane, tó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà, lẹ́nu wò, ó sọ pé: “Nígbà tí mo dé sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní 1978, mo rò pé ọjọ́ ti pẹ́ tí ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti yanjú àwọn ìṣòro rẹ̀ nípa kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, mo rò pé wọ́n ti ń bá àwọn adúláwọ̀ lò lọ́gbọọgba gẹ́gẹ́ bí aráàlú. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni mo sì ti ri í pé òótọ́ nìyẹn. Ó dà bí ẹni pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti rìn jìnnà lórí yíyanjú ìṣòro yìí ju bí Gúúsù Áfíríkà ti ṣe. Ara mí gbọ̀n nígbà tí mo wá rí i pé àwọn ènìyàn kò tí ì fi bẹ́ẹ̀ ṣàtúnṣe.” Kí ló fà á tó fi tètè ṣàwárí tó múni ta gìrì yẹn?
Mathabane sọ pé: “Wákàtí táwọn èèyàn máa ń fi ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà hàn jù lọ ní Amẹ́ríkà ni aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday.” Ó ṣàkíyèsí pé nínú ṣọ́ọ̀ṣì pàápàá, àwọn èèyàn kì í fẹ́ jọ́sìn pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn. Ó wá béèrè pé: “Báwo ni nǹkan ó ṣe wá rí láwọn ọjọ́ yòókù nínú ọ̀sẹ̀?” Nígbà tí Mathabane ń sọ nípa bí ẹ̀kọ́ ìwé ṣe lè mú ìyípadà ojú ẹsẹ̀ wa, ó ní: “Ẹ̀kọ́ ìwé yóò mú kí o gbà pé ènìyàn kan náà ni gbogbo wa.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kíkẹ́kọ̀ọ́ ni ìdáhùn rẹ̀, àmọ́, wọ́n dábàá ẹ̀kọ́ tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bí èyí tó ṣe pàtàkì jù. Dájúdájú, Bíbélì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ẹ̀tanú ẹ̀yà kúrò pátápátá—kódà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìkórìíra ẹ̀yà ti wọ́pọ̀. Àwọn ènìyàn láti onírúurú ẹ̀ya àti orílẹ̀-èdè ń kóra jọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nínú òfin àti ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Wọn kì í gbégbá owó kiri nígbà ìpàdé wọ̀nyí. A fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ síbẹ̀!