“Bí Iyọ̀ Bá Pàdánù Okun Rẹ̀”
ATI jagun nítorí rẹ̀. A ti ná an bí owó rí. Ní China ìgbàanì, táa bá ń sọ̀rọ̀ ohun tó ṣeyebíye, lẹ́yìn góòlù, òun lọpọ́n sún kàn. Bẹ́ẹ̀ ni, ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ka iyọ̀ sí nǹkan pàtàkì. Títí dòní olónìí, wọ́n fi ń ṣe ẹ̀pa tí wọ́n ń fi sójú ọgbẹ́ àti oògùn apakòkòrò, káàkiri àgbáyé ni wọ́n sì ti ń lò ó láti mú oúnjẹ dùn àti láti má ṣe jẹ́ kí nǹkan tètè bà jẹ́.
Pẹ̀lú àwọn àǹfààní iyọ̀ àti ìlò rẹ̀ yìí, kò yani lẹ́nu pé a lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, Òfin Mósè pa á láṣẹ pé a gbọ́dọ̀ fi iyọ̀ sí ohunkóhun táa bá fi rúbọ lórí pẹpẹ sí Jèhófà. (Léfítíkù 2:13) Kì í ṣe nítorí pé kí ẹbọ náà lè dùn la ṣe ní kí wọ́n fi iyọ̀ sí i o, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé iyọ̀ kì í tètè jẹ́ kí nǹkan bà jẹ́ tàbí dómùkẹ̀.
Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, èyí táa mọ̀ bí ẹni mowó, Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:13) Nípasẹ̀ gbólóhùn yìí, ohun tí Jésù ń sọ ni pé bí wọ́n ṣe ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run, yóò pa ìwàláàyè àwọn tó bá tẹ́tí sí wọn mọ́, tàbí kó gba ẹ̀mí wọn là. Lóòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìbàjẹ́ wà láwùjọ tí àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò ń gbé, tó sì wà níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ yìí yóò dáàbò bò wọ́n, kò ní jẹ́ kí ìwà wọn bà jẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí wọ́n dómùkẹ̀ nípa tẹ̀mí.—1 Pétérù 4:1-3.
Ṣùgbọ́n, Jésù ń bá ìkìlọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá pàdánù okun rẹ̀, . . . kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe kí a dà á sóde, kí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.” Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, Albert Barnes, ń ṣàlàyé lórí kókó yìí, ó wí pé, iyọ̀ tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ̀ “jẹ́ èyí tó ní pàǹtí, èyí tí koríko àti iyẹ̀pẹ̀ wà nínú rẹ̀.” Nítorí náà bí iyọ̀ yẹn bá lọ dòbu, “koríko àti iyẹ̀pẹ̀ gèlètè” ni yóò ṣẹ́ kù. Barnes sọ pé: “Èyí kò wúlò fún ohunkóhun, àyàfi . . . táa bá máa dà á sójú ọ̀nà, tàbí ká dà á sí títì, bí ìgbà táa bá da taàrá sílẹ̀.”
Láti lè kọbi ara si ìkìlọ̀ yìí, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe dẹ́kun jíjẹ́rìí fún gbogbo ènìyàn, ó tún yẹ kí wọ́n ṣọ́ra láti má ṣe ṣubú sínú àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, díẹ̀díẹ̀ ni ipò tẹ̀mí wọn yóò bà jẹ́, ó sì lè di èyí tí kò wúlò mọ́, kó wá dàbí ‘iyọ̀ tó ti pàdánù okun rẹ̀.’