ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/1 ojú ìwé 32
  • Wọ́n “Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n “Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/1 ojú ìwé 32

Wọ́n “Bẹ̀rù Ọlọ́run Tòótọ́”

WÀHÁLÀ ńlá ni àwọn Hébérù agbẹ̀bí, ìyẹn Ṣífúrà àti Púà, dojú kọ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lóko ẹrú ní Íjíbítì. Kí Fáráò lè wá nǹkan ṣe sí àwọn àtọ̀húnrìnwá tó ń pọ̀ sí i ṣáa yìí, ló fi pàṣẹ fún àwọn obìnrin wọ̀nyí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù . . . , bí ó bá jẹ́ ọmọkùnrin ni, kí ẹ fi ikú pa á.”—Ẹ́kísódù 1:15, 16.

Ṣífúrà àti Púà “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,” nítorí náà wọ́n lo ìgboyà “wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Íjíbítì ti sọ fún wọn.” Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dá àwọn ọmọkùnrin náà sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgboyà wọn yìí lè kó wọn sí yọ́ọ́yọ́. Jèhófà “ṣe dáadáa sí àwọn agbẹ̀bí náà,” ó sì san èrè fún wọn nítorí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí wọ́n ṣe.—Ẹ́kísódù 1:17-21.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà mọyì àwọn tó ń sìn ín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Ṣífúrà àti Púà ṣe gba ìgboyà, ó kan lè wò ó bí iṣẹ́ àánú lásán. Ó ṣe tán, kò sí obìnrin kan tí orí ẹ̀ pé tó lè máa gbẹ̀mí ọmọ kékeré tí ò dá nǹkan kan mọ̀! Síbẹ̀, kò sí àní-àní pé Jèhófà ti ní láti wò ó pé àwọn kan ṣáà wà, tí ìbẹ̀rù ènìyàn ti mú kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí kò bójú mu rárá. Ó mọ̀ pé kì í ṣe inú rere nìkan ló sún àwọn agbẹ̀bí wọ̀nyí ṣe ohun tí wọ́n ṣe, bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì tún jẹ́ olùfọkànsìn pẹ̀lú.

Ó mà yẹ ká kún fún ìmoore o, pé a ń sin Ọlọ́run tó ń kíyè sí òdodo wa! Lóòótọ́, ó lè máà sí èyíkéyìí nínú wa tó tí ì dojú kọ irú ìdánwò ìgbàgbọ́ tí Ṣífúrà àti Púà kojú. Síbẹ̀, nígbà tí a bá dúró gbọn-in fún ohun tó tọ́—bóyá nílé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́ wa, tàbí lábẹ́ ipò èyíkéyìí mìíràn—Jèhófà kì í fojú yẹpẹrẹ wo ìdúróṣinṣin onífẹ̀ẹ́ tí a fi hàn. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, òun “ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Dájúdájú, “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́