“Ìfaradà Ńlá Tí Ìgbàgbọ́ Mú Kó Ṣeé Ṣe”
ỌDÚN 1998 ni a mú ìwé tuntun kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe lámèyítọ́ rẹ̀ jáde lédè Faransé, orúkọ rẹ̀ ni Les Témoins de Jéhovah face à Hitler (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Wà Á Kò Pẹ̀lú Hitler), Guy Canonici ló ṣe ìwé yìí. Nínú ìfáárà ìwé náà, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé náà tí kò sẹ́ni tó jẹ́ kóyán rẹ̀ kéré láwùjọ, François Bédarida, kọ̀wé pé: “Kò síwèé táa fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gbà báyìí rí. Kì í kàn ṣe nítorí pé a kọ ọ́ lásán, ṣùgbọ́n nítorí pé ó bọ́ sákòókò tó dáa. . . . Táa bá yọwọ́ àwọn ọ̀gágun kúrò, tá ló mọ itú táa fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa lábẹ́ Ìjọba Nazi? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo ọdún méjìlá tí ìjọba náà fi ṣàkóso, ló fi ṣenúnibíni sí wọn, bó ti ń ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń fìyà gbo wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n tún fi àjẹkú-ìyà tí ń da jìnnìjìnnì boni pá wọn lórí nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ìyà tí wọ́n jẹ nítorí ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ wọn kò kéré rárá. Èé ṣe tí wọ́n fi gbàgbé àwọn Kristẹni wọ̀nyí nínú ìtàn? . . .
“Kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe irú inúnibíni burúkú, tí kò dáwọ́ dúró bẹ́ẹ̀ sí ẹ̀ya ẹ̀sìn kékeré, tó wà káàkiri, tó jẹ́ pé kò lólùgbèjà yìí? Kókó ohun tó rúni lójú ọ̀hún gan-an nìyí. Kì í kàn ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Jámánì wulẹ̀ jẹ́ ìba díẹ̀ nínú àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè náà nìkan ni—ìṣirò táa ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ fi hàn pé wọn ò ju nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] lọ nínú àwọn olùgbé tó lé ní ọgọ́ta mílíọ̀nù—àmọ́ ṣáá o, aráàlú tó lẹ́mìí àlàáfíà ni wọ́n, àwọn tó ń bọ̀wọ̀ fún òfin, tí wọn kì í sì í bẹ́nikẹ́ni fa wàhálà, tó jẹ́ pé tiwọn ò ju pé kí wọ́n ṣáà ti ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì tọ àwọn ọmọ wọn dáadáa. . . .
“Inúnibíni yìí dé sí àwọn onígbàgbọ́, tí wọ́n lẹ́mìí ìfàyàrán-nǹkan, àwọn tó gbà pé bó ti wù ó rí àwọn yóò ja àjàyè, wọ́n lẹ́mìí ìfaradà, agbára ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù Kristi nìkan tó láti borí gbogbo àtakò èyíkéyìí tó lè dé bá wọn, bẹ̀rẹ̀ látorí èyí tó lè wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá Orílẹ̀-Èdè yìí tí wọ́n ṣeni bí ọṣẹ́ ti ń ṣojú—títí dórí fífọwọ́ ọlá gbáni lójú àti pípáni nítorí ẹ̀sìn ẹni.”
Ìtàn ńlá ni ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ Kristẹni wọn nígbà tí wàhálà àìfàyègbẹ̀sìn mìíràn ń lọ lọ́wọ́ jẹ́. Nígbà tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò ìwé tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, ìwé ìròyìn Kátólíìkì kan lédè Faransé, La Croix, fi kún un, lọ́nà tí ó múni lami lójú, pé: “Nínú díẹ̀ táa mọ̀ nípa ìtàn wọn, Guy Canonici ti kó òbítíbitì ẹ̀rí jọ, èyí tí kò jẹ́ kí èèyàn mọ ohun tí yóò sọ mọ́ nípa ìfaradà ńlá tí ìgbàgbọ́ wọn mú kó ṣeé ṣe, èyí tí wọn fi àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn jù lọ sọ jáde, ìgbàgbọ́ tó jẹ́ pé títí dópin, kò ṣeé bà jẹ́, àní láàárín àwọn ọmọdé pàápàá. Ìrántí yìí yẹ kó jẹ́ ìpìlẹ̀ kan fún awuyewuye tí ń lọ lọ́wọ́ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jẹ́ Kristẹni tó.”