Iṣẹ́ àti Ìsinmi, Ìkan Ò Gbọ́dọ̀ Pàkan Lára
“Ẹ̀WÙ tó dáa ni ìsinmi jẹ́, àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ ìgbà gbogbo ṣáá la ó máa wọ̀ ọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni òǹkọ̀wé kan tí kò fẹ́ ká mọ orúkọ òun fi ṣàkàwé bí ìsinmi ti ṣe pàtàkì tó. Àmọ́ ṣá o, ó fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó gba gbogbo àkókò wa débi tí a ò fi ní ráyè fún ìgbòkègbodò mìírán tó lè ṣeni láǹfààní.
Sólómọ́nì, ìkan lára àwọn tó kọ Bíbélì lábẹ́ ìmísí mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí. Ọlọ́gbọ́n ọba yìí sọ àṣejù méjì táa gbọ́dọ̀ yẹra fún. Èkíní, ó ní: “Arìndìn ká ọwọ́ rẹ̀ pọ̀, ó sì ń jẹ ẹran ara òun tìkára rẹ̀.” (Oníwàásù 4:5) Bẹ́ẹ̀ ni, fífà dìẹ̀dìẹ̀ lè sọni di abòṣì. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó tiẹ̀ lè pa ìlera ọ̀lẹ naà lára, tàbí kò sọ ayé ẹ̀ dìdàkudà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan wà tó jẹ́ pé àṣekú iṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe. Sólómọ́nì fi gbogbo iṣẹ́ àṣekúdórógbó tí wọ́n ń ṣe wé “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:4.
Abájọ tí Sólómọ́nì fi gbani nímọ̀ràn pé ká ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ní: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Ó yẹ kéèyàn “rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀”—ìyẹn ni pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó yẹ kó gbádùn àwọn ohun tó ti fi òógùn ojú rẹ̀ kó jọ. (Oníwàásù 2:24) Kò sì yẹ kó jẹ́ pé iṣẹ́ ṣáá ló máa gba àkókò wa. A ní láti lò lára àkókò táa ní fún ìdílé wa. Sólómọ́nì tẹnu mọ́ ọn pé, iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run ni ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù lọ fún wa, kì í ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. (Oníwàásù 12:13) Ṣé oò sí lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó?