“Àbẹ̀wò Mi sí Gbọ̀ngàn Ìjọba”
Láti kọ́lẹ́ẹ̀jì tí Lauraa ti ń kàwé la ti rán an pé kó lọ sílé ìsìn kan nígbà tí ìsìn wọn bá ń lọ lọ́wọ́, kó sì kọ̀ròyìn nípa ohun tó bá rí níbẹ̀. Ló bá pinnu pé ilé ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun yóò lọ, ó pe àkọlé àròkọ rẹ̀ ní, “Àbẹ̀wò Mi sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Kí ni Laura rí tó yàtọ̀ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí? Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó mẹ́nu kàn nìyí.
Àwọn Ọmọdé: “Inú ilé kan náà ni gbogbo ọmọdé àtàwọn àgbààgbà jókòó sí. Ní gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì tí mo ti lọ rí, àwọn ọmọ kì í jókòó sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ni wọ́n máa ń lọ.”
Ìṣọ̀kan Ẹ̀yà: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń wá láti inú ẹ̀yà èdè kan tàbí ẹ̀yà ìran kan pàtó. . . . Àmọ́ ṣá o, ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣe ni gbogbo wọn máa ń jókòó pa pọ̀, wọn ò gbà pé kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa jókòó sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.”
Wọ́n Lọ́yàyà: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá bá mi, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá mi sọ̀rọ̀. . . . Àwọn kan tiẹ̀ béèrè bóyá mo lẹ́nì kan tó ń bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, n kò kà á sí pé wọ́n ń yọ mí lẹ́nu. Wọ́n . . . jẹ́ kí n pinnu fúnra mi.”
Wọn Kì í Gbégbá Owó Kiri: “Ohun kan tó yà mí lẹ́nu jù lọ ni pé kò sí ẹni táa gbowó igbá lọ́wọ́ ẹ̀. . . . Gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì tí mo ti lọ ló jẹ́ pé nínú kíláàsì àwọn ọmọdé pàápàá wọ́n máa ń gba ìdáwó níbẹ̀.”
Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́rin àbọ̀ [90,000] ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà káàkiri àgbáyé. Oò ṣe kúkú lọ séyìí tó sún mọ́ ọ jù lọ?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ mìíràn la lò.