ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 32
  • Kíkojú Ìpèníjà Títọ́ Ọmọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkojú Ìpèníjà Títọ́ Ọmọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 32

Kíkojú Ìpèníjà Títọ́ Ọmọ

TÍTỌ́ àwọn ọmọ lóde òní jẹ́ ìpèníjà ńlá fún àwọn òbí, pàápàá àwọn tó jẹ́ ọ̀dọ́langba. Ìwé ìròyìn The Gazette ti Montreal, Kánádà, ròyìn pé fífi ọtí líle àti oògùn líle dánra wò ti di “ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà.” Ó tẹnu mọ́ ọ pé “ẹrù iṣẹ́ [àwọn òbí] ló jẹ́ láti tètè máa kíyè sí bí ìwà àwọn ọ̀dọ́langba [wọn] ṣe ń yí padà.”

Kí ló yẹ kí àwọn òbí máa ṣọ́ tó lè fi irú àwọn ìṣòro aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà bẹ́ẹ̀ hàn? Àwọn àmì kan táa lè fojú rí, ní tí ìmọ̀lára, àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí Ẹgbẹ́ Olùtọ́jú Àwọn Ọmọdé àti Àwọn Aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe kìlọ̀kìlọ̀ rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú kó máa rẹni fún ìgbà pípẹ́, kí ìwà àti ìṣesí ẹni yí padà, títilẹ̀kùn pa mọ́ra ẹni sínú yàrá, ṣíṣàtakò ṣáá, àti rírú òfin ìjọba.

Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọn má bàá fi irú ohun tó lè pani lára bẹ́ẹ̀ dánra wò kí wọ́n sì wá fojú winá àwọn àbájáde búburú tó ń ní? Ọ̀mọ̀wé Jeffrey L. Derevensky, ti Yunifásítì McGill, gbà gbọ́ pé láwọn ọdún tọ́mọ kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ fàlàlà bá wà, táa sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé bíbọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ní ń jẹ́ káyé ẹni rójú, ìwọ̀nyí lè dín àwọn ìṣòro kù lọ́jọ́ iwájú. Ìwé ìròyìn The Gazette tún fi kún un pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ máa ń fẹ́ ká túbọ̀ fún wọn lómìnira nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, síbẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba ṣì nílò “ìtọ́sọ́nà, ìtìlẹ́yìn, ìlànà àti ìfẹ́ tí àwọn òbí wọ́n ń pèsè.” Àwọn àkíyèsí wọ̀nyí ń tún òwe inú Bíbélì yẹn sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Ọlọ́run fún àwọn òbí nímọ̀ràn láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere, alábàákẹ́gbẹ́, olùbánisọ̀rọ̀, àti olùkọ́.—Diutarónómì 6:6, 7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́