Nígbà Tí ‘Ẹ̀fúùfù Bá Ṣọwọ́ Òdì sí Wa’
Nígbà tí òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Máàkù, ń ṣàpèjúwe ohun tí ojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí, bí wọ́n ṣe ń jìjàdù láti tu ọkọ̀ wọn sọdá Òkun Gálílì, ó sọ pé wọ́n “dojú kọ ìṣòro nínú títukọ̀ wọn, nítorí ẹ̀fúùfù ṣọwọ́ òdì sí wọn.” Bí Jésù ṣe wà ní etídò náà, ó rí ìṣòro wọn, lọ́nà tó fi iṣẹ́ ìyanu hàn ó rìn lórí òkun náà títí ó fi dé ọ̀dọ̀ wọn. Máàkù sọ pé, nígbà tí “ó . . . gòkè sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn, ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀.”—Máàkù 6:48-51.
Òǹkọ̀wé Bíbélì yìí kan náà ròyìn pé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣáájú ìyẹn, “ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá kan bẹ́ sílẹ̀.” Ní ti ìyẹn, Jésù “bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná . . . , ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.”—Máàkù 4:37-39.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa ò láǹfààní àtirí irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ lónìí, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nínú wọn. Gẹ́gẹ́ bí aláìpé ènìyàn tó ń gbé ní àkókò eléwu, a ò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù ìpọ́njú. (2 Tímótì 3:1-5) Àní, nígbà mìíràn a lè rò pé wàhálà tó so mọ́ ìṣòro tiwa fúnra wa tó ẹ̀fúùfù líle. Àmọ́, ọ̀nà àbáyọ wà! Jésù nawọ́ ìkésíni náà pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.
Nígbà tó bá dà bíi pé ‘ẹ̀fúùfù ṣọwọ́ òdì sí wa,’ a lè ní “ìparọ́rọ́ ńláǹlà” lọ́kàn wa. Lọ́nà wo? Nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Jèhófà Ọlọ́run tí kì í yẹ̀.—Fi wé Aísáyà 55:9-11; Fílípì 4:5-7.