Ìwé Ẹ̀rí Ìgbóríyìnfúnni
OHUN tí Àjọ Àwọn Oníròyìn Ilẹ̀ Áfíríkà àti Ilẹ̀ Kóńgò Tó Wà fún Ìtẹ̀síwájú [AJOCAD] ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Kóńgò ń fúnni nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí “èrè fún àwọn èèyàn tàbí àwọn àjọ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí wọ́n bá tayọ nínú kíkópa lórí ọ̀ràn ìdàgbàsókè [ilẹ̀ Kóńgò].”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Ìwé Ẹ̀rí Ìgbóríyìnfúnni yìí ní November 17, 2000, nítorí “ipa tí wọ́n kó nínú ìtẹ̀síwájú àwọn ọmọ ilẹ̀ Kóńgò [nípasẹ̀] ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wọn.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn Le Phare ti Kinshasa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwé ẹ̀rí náà, ó sọ pé: “Bóyá la fi lè rí ọmọ ilẹ̀ Kóńgò kan tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tàbí àwọn ìwé mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde kò tíì tẹ̀ lọ́wọ́ rí. Àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ń [jíròrò] gbogbo apá ìgbésí ayé.” Àpilẹ̀kọ náà tún mẹ́nu kàn án pé àwọn ìtẹ̀jáde náà fi “bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro òde òní” hàn, ó sì ń tọ́ka sí “ohun náà gan-an tó ń fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́.” Ẹ̀dà Jí! kọ̀ọ̀kan “kì í dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú, kì í sì í gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ.” Ní àfikún sí i, àwọn ìtẹ̀jáde náà gbé “ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe ní ti ayé kan tí ó kún fún àlàáfíà, tí ó sì jẹ́ aláìléwu, tí ó máa tó rọ́pò ètò àwọn nǹkan búburú, aláìlófin ti ìsinsìnyí.”
Gẹ́gẹ́ bí àjọ AJOCAD ṣe sọ ọ́, ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ àwọn ará Kóńgò. Níwọ̀n bí a ti lè rí wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ìhìn wọn tí ń fúnni nírètí lè ṣàǹfààní fún ìwọ náà pẹ̀lú.
Jọ̀wọ́ wo ìsọfúnni tó wà nísàlẹ̀ láti rí i bí o ṣe lè jàǹfààní nínú wọn.