ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 12/15 ojú ìwé 28
  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ fún Àwọn Ọmọ Yín Lóhun Tí Wọ́n Nílò!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ fún Àwọn Ọmọ Yín Lóhun Tí Wọ́n Nílò!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 12/15 ojú ìwé 28

Ẹ̀yin Òbí—Ẹ fún Àwọn Ọmọ Yín Lóhun Tí Wọ́n Nílò!

ÀWỌN ọmọ nílò ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí onífẹ̀ẹ́, àgàgà látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Ìdí nìyẹn tí olùkọ́ni kan ní Brazil, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tania Zagury, fi sọ pé: “Ohun tí gbogbo ọmọdé ń fẹ́ ni pé káwọn ṣáà máa ṣe fàájì. Ó sì di dandan kó ní ààlà. Àwọn òbí ló sì yẹ kó ṣe èyí. Bí wọn ò bá ṣe é, ọwọ́ kò ní ká àwọn ọmọ náà mọ́.”

Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ipa tí àwùjọ tó gbàgbàkugbà, tó ń jẹ́ káwọn èèyàn lẹ́mìí kóńkó-jabele, ti ní lórí àwọn èèyàn lè jẹ́ kó ṣòro láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà lókè yìí. Ibo ni káwọn òbí wá yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run mọ̀ pé àwọn ọmọ wọn jẹ́ “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Sáàmù 127:3) Nítorí náà, wọ́n ń yíjú sí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fún ìtọ́sọ́nà láti tọ́ àwọn ọmọ náà. Fún àpẹẹrẹ, Òwe 13:24 sọ pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.”

Lílò tí Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀pá” kò fi dandan túmọ̀ sí kìkì ìfìyàjẹni; ó jẹ́ ìtọ́nisọ́nà, ní ọ̀nà èyíkéyìí tá a lè gbà fúnni. Ká sọ tòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ní ohun tí ọmọdé kan nílò láti yí ìwàkíwà rẹ̀ padà. Òwe 29:17 sọ pé: “Na ọmọ rẹ, yóò sì mú ìsinmi bá ọ, yóò sì fún ọkàn rẹ ní ọ̀pọ̀ adùn.”

Àwọn ọmọ nílò ìbáwí onífẹ̀ẹ́, kí wọ́n lè jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́. Irú ìtọ́sọ́nà aláìgbagbẹ̀rẹ́ tó sì tún jẹ́ ti onínúure bẹ́ẹ̀ ń fi ẹ̀rí hàn pé òbí kan bìkítà fún ọmọ rẹ̀. (Òwe 22:6) Nítorí náà, ẹ̀yìn òbí, ẹ má sọ̀rètí nù! Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn yíyèkooro, tó sì gbéṣẹ́ látinú Bíbélì, wàá múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn, àwọn ọmọ rẹ á sì bọ̀wọ̀ fún ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́