ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 2/15 ojú ìwé 32
  • Kí Ló Gbà Láti Ní Ẹ̀rí Ọkàn Mímọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Gbà Láti Ní Ẹ̀rí Ọkàn Mímọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 2/15 ojú ìwé 32

Kí Ló Gbà Láti Ní Ẹ̀rí Ọkàn Mímọ́?

“A PÀṢẸ fún Ìjọba Láti Wá Gba Ọ̀kẹ́ Kan [20,000] Owó Ilẹ̀ Brazil.” Ìròyìn kàyéfì yìí jáde gàdàgbà-gadagba nínú ìwé ìròyìn Correio do Povo ti ilẹ̀ Brazil lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Àpilẹ̀kọ náà sọ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ akólẹ́tà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Luiz Alvo de Araújo, tó ta ilẹ̀ kan fún ìjọba ìpínlẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀yìn tí Luiz fọwọ́ síwèé pé ilẹ̀ náà ti di ti ìjọba tán ló wá rí i pé owó tí wọ́n san fún òun fi ọ̀kẹ́ kan owó ilẹ̀ Brazil (ìyẹn ẹgbàá mẹ́rin [8,000] dọ́là owó Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà) lé sí iye tí wọ́n jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí!

Àtidá owó yìí padà fún ìjọba wá di iṣẹ́ ńlá. Lẹ́yìn tí Luiz ti lọ sílé iṣẹ́ ìjọba fún ọ̀pọ̀ ìgbà láìrí ọ̀nà àtidá owó náà padà ni ẹnì kan wá gbà á nímọ̀ràn pé kó gba lọ́yà, kó sì yanjú ọ̀ràn náà nílé ẹjọ́. Adájọ́ tó pàṣẹ pé kí ìjọba wá gba owó ọ̀hún kí wọ́n sì san àwọn owó táwọn fi yanjú ọ̀ràn náà sọ pé: “Ó hàn gbangba pé ẹnì kan ló ṣe àṣìṣe yìí, àmọ́ nítorí àwọn ìlànà dídíjú, kò sẹ́ni tó mọ̀ bí a ó ṣe yanjú rẹ̀. N kò rí irú ẹjọ́ yìí rí láyé mi.”

Luiz, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé pé: “Ẹ̀rí ọkàn mi tí mo ti fi Bíbélì kọ́ kò lè jẹ́ kí n pa ohun tí kì í ṣe tèmi mọ́wọ́. Mo ní láti ṣakitiyan láti dá owó náà padà.”

Ọ̀pọ̀ ló máa wo irú ìwà tó hù yìí gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣàjèjì pátápátá tàbí bí ohun tí kò ṣeé gbọ́ sétí pàápàá. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé àwọn Kristẹni tòótọ́ fojú ribiribi wo ọ̀ràn níní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gaara nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ayé. (Róòmù 13:5) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu láti ní ‘ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, kí wọ́n sì máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’—Hébérù 13:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́