ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 3/15 ojú ìwé 32
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìtàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìtàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 3/15 ojú ìwé 32

Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìtàn

IKÚ Jésù Kristi ni. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Nítorí ìdí mélòó kan ni.

Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú fi hàn pé ẹ̀dá ènìyàn lè pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run.

Ikú Kristi fún àwọn kan láǹfààní láti bá a ṣàkóso ní ọ̀run. Ó tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.

Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó lo búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ ìrúbọ onífẹ̀ẹ́ tó fi ara rẹ̀ ṣe. Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ṣé wàá ṣe ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ pé kí o wá bá wa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù. Ọjọ́ tí a ó ṣe ayẹyẹ náà lọ́dún yìí ni Thursday, March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. O lè lọ ṣe é ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ. Jọ̀wọ́ béèrè àkókò tí a ó ṣe é gan-an àti ibi tí a ó ti ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́