ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 10/1 ojú ìwé 8
  • Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Gba Àmì Ẹ̀yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Gba Àmì Ẹ̀yẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣí Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Sílẹ̀ fún Gbogbo Èèyàn Láti Wò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kí ni Gbọ̀ngàn Ìjọba?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 10/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Gbọ̀ngàn Ìjọba Kan Gba Àmì Ẹ̀yẹ

ILÉ Iṣẹ́ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àyíká ní Finland yan ọdún 2000 gẹ́gẹ́ bí “Ọdún Ìgbógo fún Ibi Rírẹwà Jù Lọ.” Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe kòkárí ètò náà sọ pé “ète tí wọ́n fi yan ibi rírẹwà jù lọ gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà ọdún náà ni láti rán gbogbo wa létí ipa tí ewéko títutù yọ̀yọ̀ ń ní lórí ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ àti lórí ìlera wa.”

January 12, 2001 ni lẹ́tà kan tó wá látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Tún Ìrísí Ojú Ilẹ̀ Ṣe ní Ìlú Finland dé sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Finland. Lẹ́tà náà ṣàlàyé pé wọ́n ti yan Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Tikkurila gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ibi tí yóò gba ògo ibi tó rẹwà jù lọ, ní ìbámu pẹ̀lú àkọmọ̀nà ọdún 2000. Ìdí ni pé ọ̀nà tí wọ́n gbà bójú tó àyíká rẹ̀ àti bí ọgbà rẹ̀ ṣe rí rèǹtèrente tayọ lọ́lá. Lẹ́tà náà fi kún un pé “ìrísí àyíká Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn àti nígbà òjò, máa ń tuni lára, ó dùn-ún wò, ò sì ti lọ wà jù.”

Wọ́n gbé àmì ẹyẹ̀ náà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rosendahl Hotel ní Tampere, Finland, níbi ayẹyẹ kan tí irínwó [400] àwọn amọṣẹ́dunjú àtàwọn oníṣòwò pésẹ̀ sí. Ẹgbẹ́ Àwọn Tó Ń Tún Ìrísí Ojú Ilẹ̀ Ṣe ní Ìlú Finland tún kọ ìsọfúnni kan tí wọ́n sọ pé káwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé jáde fáyé gbọ́, èyí tó kà pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lónírúurú ibi lórílẹ̀-èdè yìí ló lẹ́wà gan-an. Bóyá la fi rẹ́ni tó lè kọjá níbẹ̀ láìní bojú wo bí wọ́n ṣe tọ́jú àyíká ibẹ̀ tónítóní. Àpẹẹrẹ ọgbà rèǹtèrente kan ni Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Tikkurila jẹ́ látòkèdélẹ̀. Ilé náà àti ọgbà ńlá tó yí i ká para pọ̀ jẹ́ ibi ìparọ́rọ́, tó wà létòlétò.”

Gbọ̀ngàn Ìjọba igba ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [233] ló wà nílẹ̀ Finland, ọgbà ẹlẹ́wà sì yí ọ̀pọ̀ lára wọn ká. Àmọ́, ohun tó mú káwọn ilé wọ̀nyí rẹwà ní ti gidi ni jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ àti ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ káàkiri ayé máa ń fẹ́ràn gan-an, ì bá à jẹ́ èyí tó jojú ní gbèsè tàbí èyí tó ṣe kóńkóló. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fẹ́ láti bójú tó o dáadáa. Gbogbo aládùúgbò la fẹ́ kó wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa o!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́