Ayẹyẹ Ìrántí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tí Wọ́n Pa
NÍ March 7, 2002, wọ́n ṣí aṣọ lójú àmì ẹ̀yẹ ìrántí kan nílùú Körmend ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Hungary. Wọ́n fi àmì ẹ̀yẹ yìí ṣèrántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta tí ìjọba Násì pa lọ́dún 1945.
Wọ́n gbé àmì ẹ̀yẹ náà kọ́ sára ògiri orílé iṣẹ́ àwọn panápaná tó wà lójú ọ̀nà Hunyadi báyìí, níbi tí wọ́n gbé pa àwọn èèyàn náà. Wọ́n ṣe àmì ẹ̀yẹ náà ní ìrántí “àwọn Kristẹni tí wọ́n pa nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun ní March 1945. Antal Hőnisch (1911 sí 1945), Bertalan Szabó (1921 sí 1945), János Zsondor (1923 sí 1945), àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, 2002.”
Oṣù méjì péré ló kù kí Ogun Àgbáyé Kejì parí nígbà tí wọ́n pa àwọn èèyàn wọ̀nyí. Kí ló dé tí wọ́n fi pa àwọn Kristẹni wọ̀nyí? Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Hungary náà, Vas Népe, ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn tí Hitler gorí àlééfà ní ilẹ̀ Jámánì, àtàwọn Júù àtàwọn olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n dojú inúnibíni, ìfìyàjẹni, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ikú kọ bí wọn ò bá jáwọ́ nínú ẹ̀sìn wọn. . . . Ní oṣù March ọdún 1945, ìpayà ńláǹlà gbòde kan ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Hungary. . . . Apá kan ìpayà yìí ni pé kí wọ́n lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nílùú kí wọ́n sì pa wọ́n.”
Ọ̀nà méjì ni wọ́n pín ìtòlẹ́sẹẹsẹ ṣíṣí àmì ẹ̀yẹ ìrántí náà sí. Àkọ́kọ́ wáyé nínú Gbọ̀ngàn Batthyány, lára àwọn tó sọ̀rọ̀ níbẹ̀ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Szabolcs Szita, tó jẹ́ ọ̀gá ní Ibùdó Àkọsílẹ̀ Nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà nílùú Budapest; László Donáth, tó jẹ́ ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, àti Ọ̀ràn Àjọ Ẹlẹ́ni Kéréje àti Ìsìn; Kálmán Komjáthy, tó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa àwọn èèyàn náà, tó sì wá di ẹni tó ń sọ ìtàn ìlú náà báyìí. Àwọn èèyàn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta tó pésẹ̀ síbẹ̀ fẹsẹ̀ rìn gba àárín ìgboro kọjá lọ síbi tí wọ́n ti ṣe apá kejì ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà—ìyẹn ni ṣíṣí aṣọ lójú àmì ẹ̀yẹ ìrántí náà, èyí tí Olórí Ìlú József Honfi ti ìlú Körmend ṣe.
Nínú lẹ́tà ìdágbére tí Ján Žondor (János Zsondor) kọ kó tó kú, ó rọ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò. Ó kọ ọ́ pé: “Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù kọ nínú Ìṣípayá orí kejì ẹsẹ ìkẹwàá, ṣì wà lọ́kàn mi, pé: ‘Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ojú ikú.‘ . . . Ẹ sọ fáwọn èèyàn mi nílé pé kí wọ́n má ṣe banú jẹ́ o, nítorí pé tìtorí òtítọ́ ni mo ṣe kú mi ò kú ikú ọ̀daràn.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Bertalan Szabó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Antal Hőnisch
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ján Žondor