ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 6/15 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mọ Ọ̀tá Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Sátánì
    Jí!—2013
  • Ta Ni Sátánì? Ṣó Wà Lóòótọ́?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 6/15 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ Sátánì Èṣù lágbára láti mọ èrò inú èèyàn?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ ní pàtó, ó dà bíi pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ò lágbára láti mọ èrò inú wa.

Ronú lórí àwọn orúkọ tá a fi pe Sátánì ná. A pè é ní Sátánì (Alátakò), Èṣù (Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́), Ejò (tó túmọ̀ sí ohun kan náà pẹ̀lú Atannijẹ), Adẹniwò, àti Òpùrọ́. (Jóòbù 1:6; Mátíù 4:3; Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 11:3; Ìṣípayá 12:9) Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ wọ̀nyí tó fi hàn pé Sátánì lágbára láti mọ èrò inú èèyàn.

Àmọ́, ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, a ṣàpèjúwe Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 17:3; 1 Sámúẹ́lì 16:7; 1 Kíróníkà 29:17) Ìwé Hébérù 4:13 sọ pé: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” Abájọ tí Jèhófà fi fún Jésù, Ọmọ rẹ̀ lágbára láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn. Jésù tó jíǹde là á mọ́lẹ̀ kedere pé: “Èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.”—Ìṣípayá 2:23.

Bíbélì ò sọ pé Sátánì lágbára láti wá ọkàn àti èrò inú ènìyàn. Èyí ṣe pàtàkì, níwọ̀n bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mú un dá wa lójú pé àwọn Kristẹni “kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn [Sátánì].” (2 Kọ́ríńtì 2:11) Nítorí náà, a ò ní láti máa bẹ̀rù pé Sátánì láwọn agbára àrà ọ̀tọ̀ kan tá ò mọ́ nípa rẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, èyí ò túmọ̀ sí pé Elénìní wa ò mọ àìlera wa àti ibi tóun ti lè tètè rí wa mú. Sátánì ti fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kíyè sí ìṣe ẹ̀dá ènìyàn. Kò dìgbà tó bá lágbára láti mọ èrò inú wa kó tó fòye mọ bí a ṣe ń hùwà, kó tó mọ irú eré ìdárayá tá a fẹ́ràn, tàbí kó tó tẹ́tí sí àwọn ohun tá a máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìrísí ojú wa àti ìṣesí wa lè jẹ́ kó mọ ohun tá à ń rò àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa.

Àmọ́, lápapọ̀, ọgbọ́n kan náà tí Sátánì lò nínú ọgbà Édẹ́nì ló ṣì ń lò—ìyẹn ni irọ́, ẹ̀tàn, àti yíyí òtítọ́ po. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Báwọn Kristẹni ò tiẹ̀ ní láti bẹ̀rù pé Sátánì lè mọ èrò inú àwọn, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n máa ṣọ́ra fún irú èrò tí Sátánì lè gbìyànjú láti gbìn sínú ọkàn wọn. Ó fẹ́ káwọn Kristẹni di àwọn “tí a ti sọ èrò inú wọn di ìbàjẹ́, tí a sì ti fi òtítọ́ wọn ṣe ìjẹ.” (1 Tímótì 6:5) Abájọ tí ayé Sátánì fi kún fún àwọn ìsọfúnni àti eré ìnàjú tó burú jáì. Láti kápá ìṣòro yìí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ dáàbò bo èrò inú wọn nípa wíwọ “àṣíborí ìgbàlà.” (Éfésù 6:17) Wọ́n ń ṣe èyí nípa gbígbin òtítọ́ Bíbélì sínú ọkàn wọn àti nípa yíyẹra fún àjọṣe èyíkéyìí tó lè pa àwọn àti àwọn ohun búburú inú ayé Sátánì pọ̀.

Ọ̀tá apániláyà ni Sátánì. Àmọ́ ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí tiẹ̀ tàbí nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Ìwé Jákọ́bù 4:7 ki wá láyà pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Bá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, àá lè sọ ní kedere bíi ti Jésù pé, Sátánì ò ní ìdìmú kankan lórí wa.—Jòhánù 14:30.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́