Ojúlówó Ìrànwọ́ fún Àwọn Òtòṣì
NÍGBÀ tí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé, ríran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ jẹ́ ẹ lọ́kàn gan-an. Ohun tí ẹnì kan tí ọ̀ràn náà ṣojú rẹ̀ sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ni pé: “Àwọn afọ́jú ń padà ríran, àwọn arọ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé àwọn òkú dìde, a sì ń polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Mátíù 11:5) Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òtòṣì tó wà láyé lóde òní wá ńkọ́? Ǹjẹ́ ìhìn rere èyíkéyìí wà fún wọn láti gbọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, ìhìn tí ń fúnni nírètí wà!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ayé lápapọ̀ máa ń fojú di àwọn òtòṣì tí wọn ò sì kà wọ́n sí, síbẹ̀ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “A kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn ọlọ́kàn tútù kì yóò ṣègbé láé.” (Sáàmù 9:18) Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú wọ̀nyí yóò ní ìmúṣẹ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìṣàkóso ti ọ̀run, bá rọ́pò gbogbo ìṣàkóso ènìyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Jésù tó jẹ́ Ọba ìjọba ti ọ̀run yẹn “yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”—Sáàmù 72:13, 14.
Báwo ni ipò nǹkan yóò ṣe rí nígbà tí Kristi bá ń ṣàkóso ayé? Àwọn tó bá ń gbé nínú ayé tí Kristi ń ṣàkóso yóò gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bíbélì sọ nínú ìwé Míkà 4:3, 4 pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.” Kódà, Ìjọba Ọlọ́run yóò yanjú ìṣòro àìsàn àti ikú. (Aísáyà 25:8) Ayé yẹn á mà kúkú yàtọ̀ o! A lè gba àwọn ìlérí Bíbélì wọ̀nyí gbọ́ nítorí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló mí sí wọn.
Láfikún sí ìhìn tí ń fúnni nírètí yìí, Bíbélì tún ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó ń yọjú lójoojúmọ́, irú bí ọ̀nà tá a ó gbà borí àìní iyì ara ẹni, èyí tí ipò òṣì máa ń mú wá. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Kristẹni kan tó jẹ́ tálákà kọ́ jẹ́ kó mọ̀ pé Kristẹni tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ kò ṣeyebíye ju òun lọ lójú Ọlọ́run. Ìwé Jóòbù tó wà nínú Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kì í . . . ka ọ̀tọ̀kùlú sí ju ẹni rírẹlẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn jẹ́.” (Jóòbù 34:19) Bákan náà ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa.—Ìṣe 10:34, 35.