ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 10/1 ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ Ò ‘Ń Tàpá sí Kẹ́sẹ́’?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ò ‘Ń Tàpá sí Kẹ́sẹ́’?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 10/1 ojú ìwé 32

Ǹjẹ́ Ò ‘Ń Tàpá sí Kẹ́sẹ́’?

NÍ ÀKÓKÒ tí wọ́n kọ Bíbélì, kẹ́sẹ́, ìyẹn ọ̀pá gígùn kan tá a kí irin ṣóńṣó sí lórí, ni a máa ń lò fún dída ẹran àti títọ́ wọn sọ́nà. Bí ẹran kan bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò lọ, tí wọ́n sì gun ní kẹ́sẹ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀? Ńṣe ló máa dùn ún wọra.

Jésù Kristi tó ti jíǹde sọ̀rọ̀ nípa kẹ́sẹ́ nígbà tó fara han ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, tó fẹ́ lọ fàṣẹ ọba mú àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Látinú ìmọ́lẹ̀ tó lè fọ́ èèyàn lójú ni Sọ́ọ̀lù ti gbọ́ tí Jésù sọ pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Láti máa bá a nìṣó ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ.” Ọlọ́run ni Sọ́ọ̀lù ń bá jà bó ṣe ń hùwà ìkà sáwọn Kristẹni yìí, ohun tó máa pa á lára ló sì ń lépa.—Ìṣe 26:14.

Ǹjẹ́ àwa náà láìmọ̀ọ́mọ̀ lé máa ‘tàpá sí kẹ́sẹ́’? Bíbélì fi “ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n” wé kẹ́sẹ́ tí ó ń sún wa láti tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà títọ́. (Oníwàásù 12:11) Ìmọ̀ràn onímìísí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè sún wa láti tọ ọ̀nà tó dára, tá a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Tí a bá kọ̀, ó lè pa wá lára.

Sọ́ọ̀lù fi ọ̀rọ̀ Jésù sọ́kàn, ó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà, ó sì wá di Kristẹni olùfẹ́ tó ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù. Gbígbà tí a ń gba ìmọ̀ràn Ọlọ́run yóò jẹ́ kí á rí ìbùkún ayérayé gbà.—Òwe 3:1-6.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

L. Chapons/Illustrirte Familien-Bibel nach der deutschen Uebersetzung Dr. Martin Luthers

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́