‘Mo Rí Àwọn Tó Lọ́yàyà, Tí Wọ́n Nífẹ̀ẹ́, Tí Wọ́n sì Ń Bójú Tóni’
“NÍPA èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ ọ́, ìfẹ́ jẹ́ àmì tá a fi dá àwọn Kristẹni ìjímìjí mọ̀. Nígbà tí Tertullian ń kọ̀wé ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ikú Kristi, ó fa ọ̀rọ̀ yọ̀ látinú ohun táwọn tó kíyè sí àwọn Kristẹni wí, ó ní: ‘Ẹ wo bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó, ẹ sì wo bí wọ́n ti múra tán láti kú fún ara wọn.’
Ǹjẹ́ a ṣì lè rí irú ìfẹ́ yẹn nínú ayé? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, gbé lẹ́tà kan tí a gbà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brazil yẹ̀ wò. Obìnrin tó kọ lẹ́tà náà ń jẹ́ Marília, ó kọ̀wé pé:
“Nígbà tí mò ń gbé ní Villa Mercedes, nílẹ̀ Argentina, ìyá mi tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní làkúrègbé tó ń sọ eegun ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, èyí mú kó rọ láti ìbàdí wá sí ìsàlẹ̀. Ní oṣù mẹ́jọ tó kọ́kọ́ lò lórí àìsàn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí ní Villa Mercedes lo ń fìfẹ́ àti ìgbatẹnirò tọ́jú rẹ̀. Wọ́n bójú tó ohun gbogbo, wọn mú ilé rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní wọ́n sì ń se oúnjẹ fún un. Kódà nígbà tí Màmá wà nílé ìwòsàn, ẹnì kan máa ń wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tọ̀sán tòru.
“Èmi àti Màmá ti padà sí Brazil láti ìgbà yẹn, ara rẹ̀ sì ti ń yá báyìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbi tá à ń gbé nísinsìnyí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí màmá mi kọ́fẹ padà.”
Marília parí lẹ́tà rẹ̀ báyìí pé: “Lóòótọ́, èmi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí o, àmọ́ mo ti rí i pe àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́yàyà, wọ́n nífẹ̀ẹ́, wọ́n sì ń bójú tóni.”
Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn èèyàn ṣì wà tí wọ́n ń fi ìfẹ́ Kristẹni tòótọ́ ṣèwà hù. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi agbára tí ẹ̀kọ́ Jésù ní lórí ìgbésí ayé wa hàn.