Ẹ̀rí Ọkàn Tó Dára
NÍGBÀ tí Charles tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní yunifásítì kan lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ kan, fóònù alágbèérìn rẹ̀ sọ nù. Nǹkan olówó iyebíye ṣì ni fóònù yìí jẹ́ lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà.
Charles sọ pé: “Mi ò retí pé ẹnikẹ́ni lè rí i, kó sì dá a padà.” Àmọ́, ohun ìyanu ló jẹ́ fún un nígbà tó gba ìpè fóònù kan lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Ó dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ nígbà tí wọ́n ní kó wá gba fóònù alágbèérìn rẹ̀! Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ọkùnrin kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tóun àti Charles jọ wọkọ̀ kan náà ni ó bá a rí fóònù náà. Nígbà tó ń wá ẹni tó ni í káàkiri ló bá mú fóònù ọ̀hún lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sì lo nọ́ńbà tó wà lórí fóònù náà láti fi wá Charles kàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn.
Charles sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà pé: “Mo dúpẹ́ fún wíwá tí wọ́n wá mi kàn láìfi wàhálà tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó rí mi pè. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ yín tó bá mi rí fóònù alágbèérìn náà, tó mọ̀ pé èmi ni mo ni í, tó sì dá a padà fún mi. Ó ṣòro láti rí olóòótọ́ èèyàn lónìí, àmọ́ ó mórí ẹni wú pé a rí àwọn èèyàn díẹ̀ kan tí wọ́n dá yàtọ̀ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.”
Ibi gbogbo ni a ti mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Wọ́n ń fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18; 1 Kọ́ríńtì 11:1) Wọ́n mọyì rẹ̀ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ń fi ògo fún Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:16.