Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wá Sọ́dọ̀ Yín Lemọ́lemọ́?
KÁRÍ ayé, gbogbo àwọn èèyàn ló mọ̀ pé lemọ́lemọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù láti ilé dé ilé. Àwọn kan máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí máa wá sọ́dọ̀ àwọn lemọ́lemọ́, nígbà tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí. Lẹ́tà méjì tá a rí gbà láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣàlàyé ohun tó fà á.
Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Masha ní ìlú Khabarovsk sọ pé: “Ká sòótọ́, ńṣe ni mo máa ń sá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ka díẹ̀ lára ìwé ìròyìn táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe, kò sá fún wọn mọ́. Masha wá kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí mo ti kà nínú àwọn ìwé ìròyìn yẹn gbádùn mọ́ni, ó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, àní èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó ń jẹ́ kéèyàn wo ayé yìí lọ́nà tó yàtọ̀. Díẹ̀díẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí lóye ìdí táwọn èèyàn fi wà láàyè.”
Láti ìlú Ussuriysk tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà sí àríwá Vladivostok, obìnrin kan tó ń jẹ́ Svetlana kọ̀wé pé: “Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn yìí wúlò fún àkókò tá a wà yìí gan-an ni. Mo máa ń ka gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà nínú wọn. Àwọn àpilẹ̀kọ náà gbádùn mọ́ni, wọ́n kún fún ìsọfúnni, wọ́n sì máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ ṣeun o! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi nítorí pé ẹ wà fún wa tí ẹ sì ń ṣe iṣẹ́ àánú tó ṣe pàtàkì yìí.”
Káàkiri ayé, ọwọ́ pàtàkì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni [àwọn èèyàn] yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòmù 10:14) O ò ṣe fetí sí àwọn Ẹlẹ́rìí fún ìṣẹ́jú mélòó kan nígbà mìíràn tí wọ́n bá wá sọ́dọ̀ rẹ? Ìwọ náà lè gbádùn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì.