ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 3/1 ojú ìwé 28
  • Ọ̀nà Wo ni Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gbà Dà Bí Igi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Wo ni Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gbà Dà Bí Igi?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 3/1 ojú ìwé 28

Ọ̀nà Wo ni Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gbà Dà Bí Igi?

NÍGBÀ tí onísáàmù náà ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí inú rẹ̀ dún sí àwọn ìlànà Bíbélì tó sì fi àwọn ìlànà náà ṣèwà hù ní ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ pé: “Òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:1-3) Kí nìdí tí ìfiwéra yìí fi bá a mu wẹ́kú?

Igi lè wà fún àkókò gígùn gan-an kó tó kú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé àwọn igi ólífì kan tó wà lágbègbè Mẹditaréníà ti lo ẹgbẹ̀rún kan sí méjì ọdún láyé. Bákan náà ni igi osè tó wà ní àárín gbùngbùn Áfíríkà ti wà fún àkókò pípẹ́ gan-an, àwọn èèyàn sì gbà pé ẹ̀yà igi ahóyaya kan tó wà ní California tí lò tó nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlélógún [4,600] ọdún láyé. Nínú igbó, àǹfààní ni àwọn igi títóbi jẹ́ fáwọn nǹkan tó wà láyìíká wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn igi gíga máa ń ṣíji bo àwọn igi kéékèèké, ajílẹ̀ sì ní àwọn ewé rẹ̀ tó ń jábọ́ jẹ́ fún ilẹ̀ ibẹ̀.

Àwọn èèyàn kíyè sí i pé káàkiri ayé ńṣe làwọn igi tó ga jù lọ máa jọ ń dàgbà pọ̀ nínú igbó, níbi tí wọ́n ti máa ń fara ti ara wọn. Nítorí pé gbòǹgbò àwọn igi náà máa ń lọ́ mọ́ra wọn, ó máa ń rọrùn fáwọn igi tó fara ti ara wọn yìí láti kojú ìjì ju àwọn igi tó dá wà nínú pápá lọ. Bákan náà, tí gbòǹgbò igi kan bá tóbi, èyí á mú kó lè fa omi àti ajílẹ̀ tó pọ̀ tó látinú ilẹ̀. Nígbà mìíràn, gbòǹgbò àwọn igi kan lè wọnú ilẹ̀ lọ jìnnà débi pé ibi tó wọlẹ̀ dé lè gùn ju gíga igi ọ̀hún lọ tàbí kí títẹ́ rẹrẹ gbòǹgbò rẹ̀ tiẹ̀ nasẹ̀ ré kọjá ibi tí ẹ̀ka igi náà fẹ̀ dé.

Ó lè jẹ́ pé igi kan ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó ṣàlàyé pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni “máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi], kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kólósè 2:6, 7) Ní tòótọ́, kò sí bí Kristẹni kan ṣe lè dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ bí kò bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú Kristi.—1 Pétérù 2:21.

Ọ̀nà mìíràn wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbà dà bí igi? Bí àwọn igi tó wà nínú igbó kékeré kan ṣe jẹ́ alátìlẹyìn fún àwọn igi tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn tó sún mọ́ ìjọ Kristẹni ṣe jẹ́ alátìlẹyìn fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Gálátíà 6:2) Àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó dàgbà dénú, tí gbòǹgbò wọn nípa tẹ̀mí nasẹ̀ gan-an máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ àní nígbà tí wọ́n bá kojú àtakò lílekoko pàápàá. (Róòmù 1:11, 12) Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni náà lè ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí tí wọ́n bá wà lábẹ́ “ibòji” àwọn tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Róòmù 15:1) Gbogbo àwọn tó jẹ́ ara ìjọ Kristẹni kárí ayé ló ń jàǹfààní nínú oúnjẹ agbéniró nípa tẹ̀mí tí “igi ńlá òdodo,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró ń pèsè.—Aísáyà 61:3.

Inú wa mà dùn o pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ó lè dẹni tí yóò rí ìmúṣẹ ìlérí tó wà nínú Aísáyà 65:22, tó sọ pé: “Bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Godo-Foto

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́