Ọjọ́ Pàtàkì Tó Yẹ Ká Rántí
LÁLẸ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù Kristi kú, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ìṣù búrẹ́dì aláìwú àti ife wáìnì pupa, ó ní kí wọ́n jẹ, kí wọ́n sì mu. Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Lọ́dún yìí, ọjọ́ Sunday, April 4 ni ayẹyẹ ọdọọdún yìí bọ́ sí, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yóò pé jọ ní alẹ́ ọjọ́ yìí láti ṣayẹyẹ Ìrántí yìí lọ́nà tí Jésù pa á láṣẹ. A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ láti bá wa pé jọ. Jọ̀wọ́, béèrè àkókò àti ibi tí ìpàdé pàtàkì yìí yóò ti wáyé lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.