Bíbélì Ran Ọkùnrin Kan Lọ́wọ́ Láti Borí Ìdẹwò
Ìdẹwò pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé lónìí. Kì í sì í ṣe nǹkan tó rọrùn láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbà gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ ìṣòro láti gba ìkìlọ̀ Bíbélì náà pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tá a pè ní Sebastian nínú àpilẹ̀kọ yìí ń ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ Scandinavia ní orílẹ̀-èdè Poland. Ó ní láti sapá gidigidi láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́.
Gbogbo àwọn tí Sebastian jọ ń ṣiṣẹ́ ló mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ọ̀gá Sebastian mọrírì jíjẹ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́kára àti ọmọlúwàbí, nítorí náà ó fún un ní onírúurú àǹfààní iṣẹ́. Àmọ́, nítorí àǹfààní iṣẹ́ tí wọ́n fún un yìí, ó gba pè kó máa lọ sí àwọn ìpàdé iṣẹ́, eré ìnàjú oníṣekúṣe sì máa wáyé níbi ìpàdé náà.
Kò pẹ́ tí Sebastian fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì. Ó ní: “Ọ̀gá mi mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìdí nìyí tó fi fọkàn tán mi tó sì gbara lé mi. Bí mo bá sọ pé mi ò ní bá wọn kópa nínú ìpàdé náà, iṣẹ́ á bọ́ lọ́wọ́ mi, ojú mi sì rí màbo kí n tó lè ríṣẹ́ yìí. Nítorí náà, tí mo bá kàn wà níbẹ̀ tí mi ò dá sí eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe ńkọ́?”
Lẹ́yìn náà, Sebastian wá mọ púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ tí òun yóò máa ṣe níbi ìpàdé náà. Iṣẹ́ rẹ̀ ní pé kó máa “bójú tó” àwọn oníbàárà tó ti ilẹ̀ ibòmíràn wá, kó máa wá “àwọn ọmọge” tí wọ́n á bá ṣe ìṣekúṣe lọ́wọ́ alẹ́ fún wọn. Kí ni yóò ti wá ṣe ọ̀ràn náà sí?
Sebastian wá rán ọ̀gá rẹ̀ létí pé ẹ̀kọ́ tóun kọ́ nínú Bíbélì kò gba ìṣekúṣe láyè. Kò pẹ́ tí Sebastian fi mọ̀ ní kedere pé òun kò ní lè ṣe irú iṣẹ́ yìí àti pé bópẹ́bóyá òun máa fi iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀. Ó ríṣẹ́ mìíràn bó ti lẹ̀ jẹ́ pé owó rẹ̀ kéré síyẹn, àmọ́ kò sí irú ìdẹwò yìí níbẹ̀. Ní báyìí, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mọ́.
Kí ni wàá ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ tì ọ́ ṣe ìṣekúṣe tàbí tì ọ́ pé kó o gbà ìṣekúṣe láyè? Ǹjẹ́ o ṣe tán láti ṣe ìyípadà ojú ẹsẹ̀? Ohun tí Jósẹ́fù tó gbé láyé ìgbàanì ṣe nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12 ṣe sọ.