ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/15 ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Yí Àbájáde Ìṣòro Rẹ Padà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Yí Àbájáde Ìṣòro Rẹ Padà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/15 ojú ìwé 32

Ǹjẹ́ Àdúrà Lè Yí Àbájáde Ìṣòro Rẹ Padà?

TA NI kò tíì dojú kọ ìṣòro líle koko tó ju agbára rẹ̀ lọ rí? Bíbélì fi yé wa pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àdúrà lè nípa lórí àbájáde irú ìṣòro líle koko bẹ́ẹ̀.

Nígbà tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù láìṣẹ̀ láìrò, ó sọ fún àwọn tóun pẹ̀lú wọn jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún òun, ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo gbà yín níyànjú pàápàá jù lọ láti ṣe èyí, kí a lè tètè mú mi padà bọ̀ sípò sọ́dọ̀ yín.” (Hébérù 13:18, 19) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù tún sọ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn fi hàn pé ó dá a lójú pé Ọlọ́run yóò dáhùn àdúrà táwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ń gbà pé kí wọ́n tètè dá òun sílẹ̀. (Fílémónì 22) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n dá Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, ó sì padà sẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó ń ṣe.

Ṣùgbọ́n, ṣé lóòótọ́ ni àdúrà lè yí àbájáde ìṣòro rẹ padà? Ó ṣeé ṣe kó yí i padà. Àmọ́ o, rántí pé àdúrà kì í ṣe ààtò ìsìn lásán. Àdúrà jẹ́ ọ̀nà gidi kan tá a gbà ń bá Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti alágbára tí ń bẹ ní ọ̀run sọ̀rọ̀. Kò yẹ ká máa lọ́ra àtisọ ohun tá a fẹ́ gan-an jáde nínú àdúrà wa, àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn á gbọ́dọ̀ ní sùúrù láti rí bí Jèhófà yóò ṣe dáhùn àdúrà wa.

Ọlọ́run lè máà dáhùn gbogbo àdúrà ní tààràtà, ó sì lè máà dáhùn rẹ̀ bá a ṣe fẹ́ tàbí ní àkókò tá a retí pé kó dáhùn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, léraléra ni Pọ́ọ̀lù gbàdúrà nítorí “ẹ̀gún nínú ara” rẹ̀. Ohun yòówù kí ìṣòro Pọ́ọ̀lù jẹ́, Ọlọ́run ò mú un kúrò, àmọ́ ó fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró yìí tu Pọ́ọ̀lù nínú pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:7–9.

Kí ó dá àwa náà lójú pé bí Ọlọ́run ò tiẹ̀ mú ìṣòro wa kan kúrò, ó lè “ṣe ọ̀nà àbájáde kí [a] lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò tán gbogbo ìṣòro tó ń pọ́n aráyé lójú. Àmọ́ ní báyìí ná, bíbá “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀ lè yí àbájáde ìṣòro wa padà.—Sáàmù 65:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́