“Ẹ Fi Ń Polongo Orúkọ Jèhófà”
KÁÀKIRI ayé làwọn èèyàn ti mọyì ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti èkejì rẹ̀, Jí!, nítorí pé wọ́n kún fún oúnjẹ tẹ̀mí àti ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye. Lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí tí òǹkàwé kan láti Faransé kọ láìpẹ́ yìí fi hàn pé òótọ́ làwọn èèyàn mọyì àwọn ìwé ìròyìn wa yìí. Ó kọ̀wé pé:
“Obìnrin kan tí kò dàgbà púpọ̀ ni mí, Áfíríkà ni mo ti wá, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Àìpẹ́ yìí ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìwé ìròyìn yín. Nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé ìròyìn náà máa ń wù mí láti kà, mo ti ń rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa kàwé. Ọpẹ́lọpẹ́ yín, mo ti mọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí i báyìí, mo sì lè kọ lẹ́tà tí kò ní láṣìṣe púpọ̀ nínú.
“Ó yà mí lẹ́nu pé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ènìyàn, ilẹ̀ ayé àti Ẹlẹ́dàá lẹ̀ ń gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn yín. Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà rọrùn láti lóye débi pé, ńṣe ni ẹni tó ń kà wọ́n á fẹ́ di ọ̀jẹ̀wé. Kò tún sí ẹni tó lè kọ́ onírúurú èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà bíi tiyín.
“Ohun ìyàlẹ́nu ló tún jẹ́ fún mi láti rí i pé bẹ́ ẹ ṣe ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn yín jáde, ẹ ò fi ṣòwò àmọ́ ńṣe ni ẹ fi ń polongo orúkọ Jèhófà. Mo mọ̀ pé Jèhófà tẹ́wọ́ gbà yín, mó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa bá a lọ láti máa gba okun látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá kẹ́ ẹ bàa lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.”
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] ilẹ̀. Wọ́n ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè méjìdínláàádọ́jọ [148], wọ́n sì ń tẹ Jí! jáde ní èdè mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87]. Èèyàn kọ́ ni wọ́n ń fi ìwé ìròyìn wọ̀nyí bọlá fún o. Ńṣe ni wọ́n ń fi ìmọ̀ràn tá a gbé ka Bíbélì àti ìsọfúnni tó bágbà mu tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà bọlá fún Ẹlẹ́dàá, ẹni tó sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” (Aísáyà 48:17) Ǹjẹ́ kí o ṣe ara rẹ láǹfààní nípa kíka Ìwé Mímọ́ déédéé àtàwọn ìwé ìròyìn tó ń ṣàlàyé Bíbélì yìí.