“A Óò Fẹ́ Láti Sọ Pé, ‘Bẹ́ẹ̀ Ni!’”
LÁÌPẸ́ yìí, ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà gba lẹ́tà kan. Lẹ́tà náà sọ lápá kan pé:
“Anderson ọmọkùnrin wa ṣaláìsí nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Kó tó kú, ó ń sin adìyẹ méjì. Ó fẹ́ tà wọ́n kó sì fowó ẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Àmọ́ kò tíì ta àwọn adìyẹ náà tí ikú fi gbẹ̀mí ẹ̀.
“Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé kó fi owó náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, àwa òbí rẹ̀ ti wo àwọn adìyẹ náà dàgbà a sì ti tà wọ́n. À ń fi owó náà ránṣẹ́ sí i yín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Anderson. Nítorí ìlérí tí Jèhófà ṣe, ọkàn wa balẹ̀ pé láìpẹ́, àní láìpẹ́ rárá, a óò tún padà rí Anderson. A óò fẹ́ láti sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni!’ nígbà tó bá bi wá pé ṣé a ṣohun tó wà lọ́kàn òun. Àmọ́, kì í ṣe Anderson nìkan là ń retí, a tún ń wọ̀nà láti rí “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” tí yóò jíǹde.”—Hébérù 12:1; Jòhánù 5:28, 29.
Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i gbangbagbàǹgbà nínú lẹ́tà òkè yìí, ìrètí tó ń gbé àwọn Kristẹni tòótọ́ ró ni ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú àjíǹde. Ayọ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye ìdílé á mà pọ̀ o bíi ti ìdílé Anderson, nígbà tí wọ́n bá fojú gán-án-ní àwọn èèyàn tí ikú, tó jẹ́ ọ̀tá èèyàn, ti já gbà mọ́ wọn lọ́wọ́!—1 Kọ́ríńtì 15:24-26.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló fún wa ní ìrètí àjíǹde tó ń tuni nínú yìí. Ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ nínú ayé tuntun òdodo, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (2 Pétérù 3:13) Nígbà tí Bíbélì ń sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fáwọn èèyàn lákòókò yẹn, ó sọ pé: “Yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.