“Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Nìyẹn”
ỌMỌKÙNRIN ọlọ́dún márùn-ún ni Alexis tó ń gbé ní ìlú Morelia ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àwọn òbí rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì máa ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní àpéjọ àyíká kan tí Alexis bá ìdílé rẹ̀ lọ, ó rí àṣefihàn kan tó dá lórí wíwàásù láti ilé dé ilé. Ló bá yíjú sí bàbá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì béèrè pé: “Bàbá, Bàbá, kí ló dé tẹ́ ò máa lọ sóde ìwàásù?” Bàbá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Mo ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n bàa lè mọ béèyàn ṣe ń wàásù ni.” Alexis wá fi ìtara fèsì pé, “Bàbá, iṣẹ́ tó dára jù lọ tẹ́ ẹ lè ṣe nìyẹn.”
Ọmọdé yìí rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kóun ṣe ohun tí ìmọ̀ tóun ní nípa Jèhófà sọ pé kí òun ṣe. Nígbà tó sì jẹ́ pé inú ilé kan náà lòun àti àwọn ìbátan rẹ̀ méjì kan tó kéré sí i lọ́jọ́ orí jọ ń gbé, ó kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà ó sì bá àwọn ìbátan rẹ̀ wọ̀nyí sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn òbí rẹ̀ ti kọ́ ọ látinú Iwe Itan Bibeli Mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Alexis ò tíì mọ ìwé kà, àwọn àwòrán tó ń ṣàlàyé àwọn ìtàn tó wà nínú Iwe Itan Bibeli Mi jẹ́ kó mọ àwọn ìtàn tó wà nínú ìwé náà dáadáa. Ó tiẹ̀ sọ pé òun fẹ́ láti máa lọ bá àwọn èèyàn nínú ilé wọn láti sọ àwọn ohun tóun ń kọ́ nípa ète Ọlọ́run fún wọn.
Bẹ́ẹ̀ ni o, tèwe tàgbà ló lè mú ìgbésí ayé wọn bá ohun tí Jèhófà, “Ẹni Mímọ́” ń retí pé kí wọ́n ṣe mu, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní ńláǹlà ti ṣíṣe iṣẹ́ tó dára jù lọ, ìyẹn jíjẹ́rìí nípa Jèhófà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. (Aísáyà 43:3; Mátíù 21:16) Dájúdájú, ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó dára jù lọ téèyàn lè ṣe.