Ohun Tó O Lè Ṣe Nígbà Tí Gbogbo Nǹkan Bá Tojú Sú Ọ
ṢÉ KÌ Í ṣe pé gbogbo nǹkan tojú sú ọ? Ọ̀pọ̀ èèyàn ni gbogbo nǹkan tojú sú lákòókò hílàhílo tá a wà yìí, tí gbọ́nmi-si omi-ò-to ti gbilẹ̀. Gbogbo nǹkan tojú sú àwọn kan nítorí pé wọn ò níṣẹ́ lọ́wọ́. Àwọn mìíràn sì jẹ́ nítorí ipò tí wọ́n bára wọn lẹ́yìn jàǹbá kan. Síbẹ̀, ìṣòro ìdílé, àìsàn líle, tàbí ìṣòro àìní alábàárò táwọn kan ń bá yí ti mú kí gbogbo nǹkan tojú sú wọn.
Tí gbogbo nǹkan bá tojú sú ọ, ibo lo lè yíjú sí kó o lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jákèjádò ayé ló ti rí ìtùnú gbà nípa kíka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹn ló ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) O ò ṣe ka ibí yìí àtàwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn nínú Bíbélì tìrẹ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò ‘tu ọkàn rẹ nínú, yóò sì fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in.’—2 Tẹsalóníkà 2:17.
O tún lè rí ìrànlọ́wọ́ nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú ọ nípa bíbá àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà kẹ́gbẹ́. Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” Nígbà tá a bá wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni, a máa ń gbọ́ “ọ̀rọ̀ rere,” èyí ‘tó dùn mọ́ ọkàn, tó sì ń mú àwọn egungun lára dá.’ (Òwe 16:24) O ò ṣe wá sípàdé kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o lè fojú ara rẹ rí ọ̀nà tí irú àpéjọ bẹ́ẹ̀ máa gbà fún ọ lókun?
O tún lè jàǹfààní látinú agbára àdúrà. Bí àníyàn inú ayé yìí bá ń kó ìbànújẹ́ bá ọ, sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa mọ wá ju bi a ṣe mọ ara wa lọ. A lè gbára lé e pé yóò ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣèlérí fún wa pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Dájúdájú, “àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.”—Aísáyà 40:31.
Jèhófà Ọlọ́run ti fún wa ní gbogbo ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú wa. Ṣé wàá lò wọ́n?