ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 10/1 ojú ìwé 32
  • Kì Í Ṣe Eré Lásán

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kì Í Ṣe Eré Lásán
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 10/1 ojú ìwé 32

Kì Í Ṣe Eré Lásán

ÀWỌN ọmọdé fẹ́ràn eré ṣíṣe. Àmọ́, ìwé The Developing Child (Ọmọ Tó Ń Dágbà) ṣàlàyé pé, “èyí kì í ṣe erémọdé lásán. Ó dà bíi pé òun gan-an ló ń jẹ́ káwọn ọmọdé gbọ́n.” Bí àwọn ọmọdé ṣe ń ṣeré ni wọ́n ń kọ́ ọ̀nà tí wọ́n máa gba lo agbára ìmòye wọn, tí wọ́n máa gbà lóye ohun tó wà láyìíká wọn, àti ọ̀nà tí wọ́n á gbà bá àwọn ẹlòmíràn da nǹkan pọ̀.

Àtìgbà táwọn ọmọdé bá ti wá lọ́mọ ọdún mẹ́rin tàbí márùn-ún ni wọ́n ti máa ń fi ohun táwọn àgbà máa ń ṣe kún erémọdé wọn. Kódà, Jésù fìgbà kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọdé tó ń ṣeré. Àwọn kan á fẹ́ ṣeré “ìgbéyàwó,” àwọn mìíràn á fẹ́ ṣe bíi pé àwọn ń “sìnkú,” àwọn ọmọdé sì sábà máa ń bá ara wọn ṣawuyewuye nítorí pé àwọn kan lè máà fẹ́ bá wọn ṣe eré náà. (Mátíù 11:16, 17) Irú àwọn eré bí èyí lè gbin ohun pàtàkì sí ọkàn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà.

Àwọn ọmọ tó wà nínú àwòrán yìí ń ṣe eré ẹni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Kì í ṣe pé wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ti gidi o, àmọ́ èrò sísọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fáwọn èèyàn ti wá lọ́kàn wọn digbí. Ohun tí wọ́n sì ń ṣe yìí sì ṣe pàtàkì gan-an, nítorí pé Jésù pàṣẹ fún gbogbo ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì kọ́ àwọn èèyàn láti máa pa gbogbo ohun tóun ti kọ́ wọn mọ́.—Mátíù 28:19, 20.

Ayọ̀ ńlá ló yẹ kó jẹ́ fáwọn òbí tọ́mọ wọn bá ń ṣeré tó máa dà bíi pé wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó máa dà bíi pé wọ́n ń sọ àsọyé, tàbí pé wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé. Ohun táwọn ọmọdé bá rí i pé àwọn àgbà tó wà nítòsí wọn ń ṣe ni wọ́n sábà máa fi ń ṣeré. Àwọn eré Bíbélì táwọn ọmọdé máa ń ṣe fi hàn pé a ti tọ́ wọn dàgbà “ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.”—Éfésù 6:4, Bibeli Mimọ.

Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọdé kópa nínú ìjọsìn tòótọ́. Ó sọ fún Mósè pé kó pe “àwọn ọmọ kéékèèké” síbẹ̀ nígbà tó bá ń ka Òfin náà sí etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn. (Diutarónómì 31:12) Táwọn ọmọdé bá rí i pé ọ̀ràn náà kan àwọn, àwọn eré tí wọ́n bá ń ṣe á fi èyí hàn. Ọmọ tó sì ń ṣe eré pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run lòun ti ń gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó máa fi ẹsẹ̀ rẹ̀ lé ọ̀nà àtidi òjíṣẹ́ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́