Ǹjẹ́ Ó Wù Ọ́ Láti Gbé Nínú Ayé Téèyàn Ò Ti Ní Máa Bẹ̀rù?
“Inú ‘ìbẹ̀rùbojo tó lé kenkà’ là ń gbé, ọkàn wa ò sì balẹ̀ rárá’ nítorí ‘àjálù . . . tẹ́nì kan ò lè sọ bó ṣe máa rí, èyí tó lè wáyé nígbàkigbà, láìròtẹ́lẹ̀.’”
ÀWỌN ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n tún kọ sínú ìwé ìròyìn Newsweek lọ́dún tó kọjá, fi bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó ń gbé nínú ayé oníhílàhílo lónìí hàn. Jésù Kristi fi hàn pé irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ yóò túbọ̀ pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí làásìgbò yóò wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò fi ní mọ ọ̀nà àbájáde. Ó tún sọ pé àwọn èèyàn á kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tó ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ ní tiwa, kò yẹ ká máa bẹ̀rù, nítorí Jésù fi kún un pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:25-28.
Jèhófà Ọlọ́run sọ bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn ìdáǹdè yẹn, ó ní: “Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.” (Aísáyà 32:18) Jèhófà gbẹnu Míkà, wòlíì rẹ̀, sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.
Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa yàtọ̀ sí irú ìgbésí ayé tá à ń gbé lónìí! Àjálù tẹ́nì kan ò mọ̀ kò ní máa dáyà fo ọmọ aráyé mọ́. Dípò àìbalẹ̀-ọkàn àti ìbẹ̀rù tó lé kenkà, àlàáfíà àti ayọ̀ tí kò lópin ni yóò wà.