ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/1 ojú ìwé 30
  • Ìtumọ̀ Bíbélì Kan Tí Ò “Láfiwé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtumọ̀ Bíbélì Kan Tí Ò “Láfiwé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/1 ojú ìwé 30

Ìtumọ̀ Bíbélì Kan Tí Ò “Láfiwé”

ÌṢIRÒ táwọn kan ṣe fi hàn pé ó ń lọ sí oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì márùndínlọ́gọ́ta tí wọ́n tú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sí láàárín ọdún 1952 sí ọdún 1990. Ọ̀rọ̀ tí àwọn tó túmọ̀ àwọn Bíbélì náà lo láti túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú ìtumọ̀ wọn kò bára mu. Jason BeDuhn, igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn ní Yunifásítì Northern Arizona, nílùú Flagstaff, ìpínlẹ̀ Arizona, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà yẹ mẹ́jọ wò lára àwọn ìtumọ̀ náà, ó sì fi wọn wéra láti mọ bí wọ́n ṣe péye tó. Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó yẹ̀ wò. Kí ni àbájáde àyẹ̀wò rẹ̀ yìí?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé BeDuhn ò fara mọ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì yìí, síbẹ̀ ó sọ pé ó jẹ́ ìtumọ̀ kan tí ò “láfiwé,” ó ní “ó dára gan-an” ó sì “péye ní gbogbo ọ̀nà” ju àwọn kan lára àwọn tóun yẹ̀ wò. BeDuhn wá sọ pé lápapọ̀, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì “jẹ́ ọkàn lára ìtumọ̀ Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì tó péye jù lọ nínú àwọn ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun tó wà lọ́wọ́ báyìí,” ó ní òun ló sì “péye jù lọ nínú gbogbo àwọn tóun yẹ̀ wò.”—Látinú ìwé Truth in Translation: Accuracy and Bias in English Translations of the New Testament.

BeDuhn tún rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn olùtumọ̀ ló máa ń “sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́rọ̀ mìíràn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ kọjá ohun tí Bíbélì sọ kó lè bá ohun táwọn tó ń kà á lóde òní fẹ́ mu.” Àmọ́ BeDuhn jẹ́ ká mọ̀ pé Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì yìí yàtọ̀, ohun tó sì mú kó yàtọ̀ ni pé “ó péye gan-an, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú rẹ̀ bá ohun tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun ti ìbẹ̀rẹ̀ mu.”

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun fi ṣe ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀, wọ́n ní “ẹrù iṣẹ́ ńláńlá ni ó jẹ́” láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ látinú èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ níbẹ̀rẹ̀ sí èdè táwọn èèyàn ń sọ lóde òní. Ìgbìmọ̀ náà tún sọ pé: “Àwọn olùtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Olú Ọ̀run tí í ṣe Òǹṣèwé Ìwé Mímọ́, nímọ̀lára àkànṣe ẹrù iṣẹ́ sí I láti túmọ̀ àwọn èrò àti àwọn ìpolongo rẹ̀ lọ́nà pípéye bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.”

Látìgbà tí wọ́n ti tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde lọ́dún 1961 títí di àkókò yìí, èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ni wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ sí, méjì lára wọn sì jẹ́ ti àwọn afọ́jú. Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí “Májẹ̀mú Tuntun,” ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sì tún wà ní èdè mọ́kàndínlógún mìíràn, ọ̀kan lára rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn afọ́jú. A rọ̀ ẹ́ láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ òde òní tí ò “láfiwé” yìí. Èdè Yorùbá rẹ̀ náà wà pẹ̀lú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́