ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 1/1 ojú ìwé 32
  • Àkókò Oúnjẹ Kì í Ṣe Oúnjẹ Jíjẹ Nìkan Ló Wà fún O!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkókò Oúnjẹ Kì í Ṣe Oúnjẹ Jíjẹ Nìkan Ló Wà fún O!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 1/1 ojú ìwé 32

Àkókò Oúnjẹ Kì í Ṣe Oúnjẹ Jíjẹ Nìkan Ló Wà fún O!

KÒ SẸ́NI tí kì í gbádùn oúnjẹ aládùn. Tí ìjíròrò àti ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin pẹ̀lú àwọn tá a fẹ́ràn bá tún wá lọ bá a rìn, oúnjẹ náà á túbọ̀ gbádùn mọ́ni. Ọ̀pọ̀ ìdílé jọ máa ń jẹun pa pọ̀, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́. Àkókò oúnjẹ máa ń jẹ́ kí ìdílé ní àǹfààní láti sọ àwọn ohun tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe àti ohun tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ náà. Àwọn òbí tó bá ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ wọn ń sọ máa ń mọ ohun táwọn ọmọ náà ń rò lọ́kàn, wọ́n sì máa ń mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, bí ìdílé ṣe jọ ń gbádùn ara wọn nídìí oúnjẹ á jẹ́ kí ọkàn wọn túbọ̀ balẹ̀, kí wọ́n fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, èyí yóò sì mú kí nǹkan máa lọ dáadáa nínú ìdílé wọn.

Lónìí, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ìdílé láti jẹun pa pọ̀ nítorí dídí tọ́wọ́ wọn máa ń dí àti nítorí kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbà gbogbo. Láwọn apá ibì kan láyé sì rèé, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn ò fàyè gba kí ìdílé jọ máa jẹun pọ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nídìí oúnjẹ. Ńṣe làwọn ìdílé mìíràn sì máa ń tan tẹlifíṣọ̀n kalẹ̀ tí wọ́n bá ń jẹun, èyí tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè jọ sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ṣe wọ́n láǹfààní.

Ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè fi gbé ilé wọn ró. (Òwe 24:27) Láyé àtijọ́, Ọlọ́run sọ ọkàn lára àwọn ìgbà tó dára jù lọ táwọn òbí lè bá àwọn ọmọ wọn sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé wọn.’ (Diutarónómì 6:7) Táwọn òbí bá ń jẹun pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn nígbà gbogbo, èyí á fún wọn láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, àtàwọn ìlànà rẹ̀. Bó o bá ń jẹ́ kí àkókò tí ìdílé rẹ fi ń jẹun pa pọ̀ jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó sì tù yín lára, ẹ óò gbádùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ àkókò tó ń gbé yín ró. Bẹ́ẹ̀ ni o, má ṣe jẹ́ kó jẹ́ pé oúnjẹ nìkan lẹ ó máa fi àkókò náà jẹ!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́