Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tó o kà wọ́n? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Kí nìdí tí wọ́n fi yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ìbí Jésù?
Bíbélì ò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Enciclopedia Hispánica sọ pé: “Kì í ṣe pé àwọn èèyàn dìídì ṣírò ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù láti mọ ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì ní December 25, àmọ́ ọjọ́ táwọn ará Róòmù ń ṣe àjọ̀dún ìbí oòrùn ni wọ́n kàn gbé wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.” Tí àwọn ará Róòmù bá ń ṣọdún yíyọ oòrùn nígbà òtútù, ńṣe ni wọ́n máa ń filé pọn ọtí tí wọ́n á fọ̀nà rokà, wọ́n á pagbo àríyá, wọ́n á sì tún máa há ẹ̀bùn fún ara wọn.—12/15, ojú ìwé 4 àti 5.
• Ṣé ohun tí Ìṣe 7:59 ń sọ ni pé Sítéfánù gbàdúrà sí Jésù?
Rárá o. Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí. Rírí tí Sítéfánù rí Jésù nínú ìran ló mú kó darí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí Jésù ní tààràtà, tó sọ pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” Sítéfánù mọ̀ pé Ọlọ́run ti fún Jésù láṣẹ láti jí òkú dìde. (Jòhánù 5:27-29) Nítorí náà, ńṣe ló ń ké gbàjarè sí Jésù pé kó fi ẹ̀mí òun pa mọ́ títí dìgbà tí òun yóò fi ní àjíǹde.—1/1, ojú ìwé 31.
• Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ò kọ kádàrá mọ́ ẹnikẹ́ni nínú wa?
Ọlọ́run fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá, èyí tó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò kádàrá nǹkan kan mọ́ wa. Ká ní Jèhófà ti kọ gbogbo ohun tá a máa ṣe mọ́ wa, tó tún wá ń fìyà jẹ wá nítorí pé a ṣe nǹkan ọ̀hún, ńṣe lèyí máa fi hàn pé Ọlọ́run kì í ṣe onídàájọ́ òdodo àti onífẹ̀ẹ́. (Diutarónómì 32:4; 1 Jòhánù 4:8)—1/15, ojú ìwé 4 àti 5.
• Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn sọ pé iṣẹ́ ìyanu ò ṣeé ṣe?
Bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń rí i pé òye àwọn ò tíì kún tó nípa àgbàyanu ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí Ọlọ́run fi dá gbogbo àwọn ohun tó dá, àwọn kan nínú wọn ti sọ pé àwọn ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé nǹkan kan ò ṣeé ṣe mọ́. Ohun tí wọ́n kàn ń sọ báyìí ni pé àwọn ò rò pé ó lè ṣẹlẹ̀.—2/15, ojú ìwé 5 àti 6.
• Kí nìdí tí Sámúsìnì Onídàájọ́ fi sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé ọmọbìnrin àwọn Filísínì ni òun fẹ́ fi ṣe aya? (Àwọn Onídàájọ́ 14:2)
Ẹni tó bá lọ fẹ́ abọ̀rìṣà ti rú òfin Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 34:11-16) Síbẹ̀, obìnrin ilẹ̀ Filísínì yìí gan-an “ló ṣe wẹ́kú” lójú Sámúsìnì. Ìdí tí Sámúsìnì fi nífẹ̀ẹ́ sí obìnrin náà ni pé ó “ń wá àyè lòdì sí àwọn Filísínì,” ó sì rí i pé òun á rí obìnrin yìí lò fún ohun tó fẹ́ ṣe yìí. Ọlọ́run sì fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ti Sámúsìnì lẹ́yìn. (Àwọn Onídàájọ́ 13:25; 14:3, 4, 6)—3/15, ojú ìwé 26.
• Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni fún òṣìṣẹ́ ìjọba lówó tàbí kó fún un lẹ́bùn kí òṣìṣẹ́ náà lè ṣe iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe?
Kò tọ́ kí Kristẹni fún òṣìṣẹ́ ìjọba ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tàbí kó fún un ní ohun pàtàkì kan kó lè ṣe ohun tí kò bófin mu tàbí kó lè ṣe ojúsàájú. Àmọ́ téèyàn bá fún òṣìṣẹ́ ọba kan lẹ́bùn kó lè báni ṣe ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ ẹni tàbí kó má bàa jẹ́ kí ìyà tí kò tọ́ síni jẹni, ìyẹn kì í ṣe àbẹ̀tẹ́lẹ̀.—4/1, ojú ìwé 29.