Orí Ìpìlẹ̀ Wo Lò Ń kọ́ Ìgbésí Ayé Rẹ Lé?
Bí ilé kan yóò bá dúró gbọn-in kó sì wà fún ìgbà pípẹ́, ìpìlẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ lágbára. Nígbà míì, Bíbélì máa ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣe àpèjúwe.
Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Aísáyà sọ pé Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó “fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀.” (Aísáyà 51:13) Ìpìlẹ̀ yìí dúró fún àwọn ìlànà tí kò lè yí padà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. Àwọn ìlànà yìí ni ayé ń tẹ̀ lé tí kò fi tàsé ipa ọ̀nà rẹ̀ bó ṣe ń yí po, àwọn ló sì jẹ́ kí ayé fìdí múlẹ̀ gbọn-in. (Sáàmù 104:5) Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìpìlẹ̀” tí aráyé wà lórí rẹ̀. Àwọn ìpìlẹ̀ yìí ni ìdájọ́ òdodo, òfin, àti kí nǹkan máa lọ létòlétò. Àmọ́ tí àìṣèdájọ́ òdodo, ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ipá bá ‘ya àwọn ìpìlẹ̀ yìí lulẹ̀,’ ìyẹn ni pé tí wọ́n bá sọ àwọn ìpìlẹ̀ yìí di èyí tí kò lágbára mọ́, gbogbo nǹkan ò ní máa lọ létòlétò mọ́ láwùjọ.—Sáàmù 11:2-6; Òwe 29:4.
Ọ̀rọ̀ yìí tún kan àwa èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ àsọkágbá nígbà ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí òkè, ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Síwájú sí i, gbogbo ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí kì í sì í ṣe wọ́n ni a ó fi wé òmùgọ̀ ọkùnrin, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì kọlu ilé náà, ó sì ya lulẹ̀, ìwólulẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀.”—Mátíù 7:24-27.
Orí ìpìlẹ̀ wo lò ń kọ́ ìgbésí ayé rẹ lé? Ṣé orí ọgbọ́n èèyàn tí kò bá ti Ọlọ́run mu, èyí tó dà bí yanrìn tó máa jẹ́ kó wó lulẹ̀ lò ń kọ́ ọ sí ni? Àbí ńṣe lò ń kọ́ ọ sórí ìpìlẹ̀ tó lágbára bí àpáta, ìyẹn ṣíṣègbọràn sí àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi, èyí tó máa jẹ́ kó o lè la àwọn ohun tó dà bí ìjì nígbèésí ayé já?