Jèhófà Bù Kún Ìrìn Àjò Ọ̀nà Jíjìn Tí Wọ́n Rìn
ÌRÒYÌN kan wá láti orílẹ̀-èdè Kóńgò tó sọ nípa àwọn ọmọ ìyá méjì tí wọ́n pinnu láti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn gba àgbègbè kan tí ogun ti bà jẹ́. Àwọn obìnrin méjì ọ̀hún ń lọ sí Ìpàdé Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” tí wọ́n ṣe nílùú Lisala. Yàtọ̀ sí ìtọ́ni tẹ̀mí àti ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n nírètí láti gbádùn ní àpéjọ náà, wọ́n tún ń retí àtirí àwọn aṣojú tó máa wá sí àpéjọ náà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Kinshasa. Wọn ò rí ẹnikẹ́ni láti ẹ̀ka ọ́fíìsì náà fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí ogun abẹ́lé tó ń jà lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì fẹ́ lo àǹfààní tí wọ́n ní yìí láti rí àwọn tó wá látibẹ̀.
Àwọn obìnrin méjèèjì yìí wọ ọkọ̀ ojú omi kékeré láti Basankusu ìlú wọn lọ́ sílùú Lisala. Ìrìn àjò nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà ni wọ́n rìn. Wọ́n gba inú igbó wọ́n sì kọjá lórí odò méjì. Ìrìn àjò náà gbà wọ́n ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko. Níwọ̀n báwọn méjèèjì ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí ọ̀kan nínú wọn ti lo ọdún mẹ́ta nínú iṣẹ́ náà tí èkejì sì ti lo ọdún mọ́kàndínlógún, wọ́n lo àǹfààní ìrìn àjò yìí láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn èèyàn bí wọ́n ti ń lọ. Wọ́n fi nǹkan bí àádọ́fà [110] wákàtí wàásù fáwọn tí wọ́n bá pàdé lójú ọ̀nà, àwọn èèyàn sì gba igba [200] ìwé ìléwọ́ àti ọgbọ̀n ìwé ìròyìn lọ́wọ́ wọn.
Bí wọ́n ti ń lọ lórí odò náà, wọ́n ní láti máa gba àárín àwọn erinmi àti ọ̀nì tó pọ̀ lágbègbè yẹn kọjá. Wọn ò lè gba inú odò náà kọjá lálẹ́, nítorí pé ó léwu gan-an láti gbabẹ̀ nínú òkùnkùn! Wọ́n tún gba ọ̀pọ̀ ibi táwọn ọmọ ogun máa ń dúró sí tí wọ́n ń yẹ àwọn èèyàn tó ń kọjá wò.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìn àjò náà jìnnà tó sì jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, síbẹ̀ àwọn arábìnrin méjèèjì yìí láyọ̀ pé àwọn sapá láti rìnrìn àjò náà. Inú àwọn méjèèjì dùn gan-an wọ́n sì kún fún ọpẹ́ pé àwọn lè wà ní àpéjọ tó wáyé nílùú Lisala náà. Wọ́n tún láyọ̀ gidi gan-an nítorí pé wọ́n wà nínú òtítọ́. Àwọn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wá sí àpéjọ náà sì jẹ́ ìṣírí fún wọn. Lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí tí wọ́n ń padà bọ̀ wá sílé, wọ́n tún la gbogbo wàhálà yìí kọjá, wọ́n sì bá àwọn ará ilé wọn láyọ̀ àti àlàáfíà.