ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 8/15 ojú ìwé 30
  • “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ Ni Wọn Ì Bá Ti Dá Wọn Sílẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ Ni Wọn Ì Bá Ti Dá Wọn Sílẹ̀”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 8/15 ojú ìwé 30

“Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ Ni Wọn Ì Bá Ti Dá Wọn Sílẹ̀”

GENEVIÈVE DE GAULLE jẹ́ mọ̀lẹ́bí Charles de Gaulle tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Faransé nígbà kan rí. Ìgbà tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nílùú Ravensbrück ní àríwá orílẹ̀-èdè Jámánì ló bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Inú lẹ́tà kan tó kọ ní oṣù August ọdún 1945 ló ti sọ ọ̀rọ̀ tá a fi ṣe àkọlé àpilẹ̀kọ yìí.

Ní January 27, 1945, wọ́n dá àwọn tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìlú Auschwitz lórílẹ̀-èdè Poland sílẹ̀. Látọdún 1996 ni wọ́n sì ti ya ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ nílẹ̀ Jámánì láti máa fi ṣèrántí àwọn tí ìjọba Násì fìyà jẹ.

Ní January 27, 2003 tí í ṣe àyájọ́ ọjọ́ yìí, Peter Straub tó jẹ́ olórí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ Baden-Württemberg sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan fún àwọn tó pé jọ níbi ayẹyẹ náà. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “A yin gbogbo àwọn tí ìjọba Hitler fìyà jẹ nítorí ìgbàgbọ́ wọn tàbí nítorí pé wọn kò fara mọ́ ohun tíjọba náà ń ṣe, tó jẹ́ pé wọ́n múra tán láti kú dípò kí wọ́n ṣe ohun tí ìjọba náà ń fẹ́. Áà, akíkanjú ni wọ́n! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ẹlẹ́sìn tí kò ṣe ohun tí ìjọba Hitler ń fẹ́, ìyẹn ni pé wọn kò bẹ́rí fún Hitler. Wọn ò júbà Hitler àti ìjọba rẹ̀, wọ́n ò wọṣẹ́ ológun, wọn ò sì ṣiṣẹ́ èyíkéyìí tó máa ti ogun lẹ́yìn. Àwọn ọmọ wọn náà ò sì sí lára Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Ṣètìlẹ́yìn fún Hitler.”

Jésù Kristi sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi ṣe ohun tí ìjọba Hitler ń fẹ́ ni pé ó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn. Straub ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò wà lára aṣọ wọn nígbà tí wọ́n ń ṣẹ̀wọ̀n ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nìkan ni ẹlẹ́wọ̀n tó lè fúnra wọn fòpin sí ìyà àti ìnira wọn tí wọ́n bá fẹ́. Ohun tí wọ́n kàn máa ṣe ò ju pé kí wọ́n tọwọ́ bọ̀wé láti fi hàn pé àwọn ò tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀sìn àwọn mọ́.”

Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò kọ ìlànà ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀fà [1,200] lára wọn ló kú nígbà tí Hitler ń ṣèjọba. Àádọ́rinlénígba [270] làwọn aláṣẹ sì pa torí pé wọn ò ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn. Lọ́rọ̀ àti níṣe ni wọ́n fi gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

Ọ̀gbẹ́ni Ulrich Schmidt tó jẹ́ olórí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ North Rhine-Westphalia sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àkàndá èèyàn. Nígbà tí ìwé ìròyìn Landtag Intern ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ọ̀gbẹ́ni Schmidt sọ, ó ní wọn ò “yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù rárá. Nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn, wọ́n rọ̀ mọ́ ìlànà ẹ̀sìn wọn, wọ́n jẹ́ onígboyà, wọn ò sì ṣe ohun tí ìjọba Násì fẹ́ nítorí pé ó lòdì sí ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe.” Kí ó dá wa lójú pé inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí gbogbo àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìṣòro. Nínú ìwé Òwe 27:11, Bíbélì sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda United States Holocaust Memorial Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́