ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 11/1 ojú ìwé 32
  • Wọ́n Ń Sọ Ìhìn Rere Fáwọn Adití

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ń Sọ Ìhìn Rere Fáwọn Adití
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 11/1 ojú ìwé 32

Wọ́n Ń Sọ Ìhìn Rere Fáwọn Adití

“Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ń mú wá!” Gbólóhùn yìí ni olùdarí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan nílùú Navalcarnero, lágbègbè Madrid, lórílẹ̀-èdè Sípéènì sọ láìpẹ́ yìí nípa báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wá sílé ìtọ́jú àwọn arúgbó tó ti ń ṣiṣẹ́. Kí ló fà á tó fi sọ bẹ́ẹ̀?

Adití làwọn bíi mélòó kan lára àwọn tó ń gbé ilé ìtọ́jú tí wọ́n ń pè ní Rosas del Camino yìí. Àmọ́, nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti sapá láti kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Sípéènì, ó ṣeé ṣe fún wọn láti bá àwọn adití tó ń gbé nílé ìtọ́jú náà sọ̀rọ̀. Olùdarí náà yin àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí fún bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn láti kọ́ àwọn èèyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́ àkànṣe yìí ní nǹkan tẹ̀mí láìgbowó. Ó ṣàkíyèsí pé ẹ̀kọ́ tó dá lórí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń kọ́ àwọn tó ń gbé nílé ìtọ́jú yìí ń ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn àgbàlagbà yìí mọrírì bí àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe ń wá sọ́dọ̀ wọn gan-an, àgàgà àwọn tí kò ríran tàbí tí kò gbọ́ràn dáadáa lára wọn.

Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Eulogio, tí kò ríran tó sì tún jẹ́ adití, ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Lọ́jọ́ kan, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, bàbá àgbàlagbà kan wá fún Ẹlẹ́rìí náà ní ewì kan táwọn tó ń gbé nílé ìtọ́jú náà kọ láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Àkọlé ewì náà ni, “Irú Ẹni Táwọn Ẹlẹ́rìí Jẹ́.” Ewì náà kà lápá kan pé: “Wọ́n ń gbé ìgbésí ayé tó dára wọ́n sì ń hùwà tó bójú mu, àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni wọ́n sì ti ń rí ọgbọ́n tó ń fún wọn láyọ̀. Wọ́n ń lọ sílé àwọn èèyàn lemọ́lemọ́ nítorí pé wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà.”

Ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn Ẹlẹ́rìí ní nínú Jèhófà yìí gan-an lohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn kọ́ èdè àwọn adití lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Lọ́nà yìí, ó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ ìhìn rere tí ń fúnni níṣìírí àti ìrètí tó wà nínú Bíbélì fún àwọn adití.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́