‘Ibi Tí Wọ́n Kọ Ọ̀rọ̀ Bíbélì sí, Èyí Tí Ọjọ́ Rẹ̀ Pẹ́ Jù Lọ’
NÍ ỌDÚN mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, àwọn awalẹ̀pìtàn ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣàwárí ohun pàtàkì kan. Wọ́n rí àkájọ ìwé kékeré méjì tí wọ́n fi fàdákà ṣe, èyí tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Bíbélì sí lára, nínú ihò ìsìnkú kan tó wà níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Àfonífojì Hínómù ní Jerúsálẹ́mù. Kí àwọn ará Bábílónì tó pa ìlú Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti ṣe àwọn àkájọ ìwé náà. Díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí Mósè fi súre, tó wà nínú Númérì 6:24-26, wà nínú wọn. Ọ̀pọ̀ ibi ni Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, sì ti fara hàn nínú àkájọ ìwé méjèèjì. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyẹn ni “ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ìgbàanì tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ, èyí tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì èdè Hébérù wà lára rẹ̀.”
Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọjọ́ àwọn àkájọ ìwé náà kò pẹ́ tó báwọn awalẹ̀pìtàn ṣe sọ, wọ́n ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ wọ́n. Ìdí kan tí wọ́n fi ń ṣiyèméjì ni pé kò rọrùn láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ inú wọn torí pé fọ́tò àwọn àkájọ ìwé tó kéré gan-an yìí tí wọ́n kọ́kọ́ yà kò dára tó. Kí awuyewuye tó wà lórí àkókò tí wọ́n kọ àwọn àkájọ ìwé náà lè yanjú, àwọn ọ̀mọ̀wé kan lọ ṣe àyẹ̀wò tuntun. Wọ́n lo àwọn kámẹ́rà àti ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde láti fi ya fọ́tò àwọn àkájọ ìwé náà, kí ohun tó wà nínú wọn lè hàn kedere. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n tẹ àbájáde ìwádìí wọn jáde. Kí lohun táwọn ọ̀mọ̀wé ọ̀hún wá sọ nípa ìgbà tí wọ́n kọ àkájọ ìwé wọ̀nyẹn?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn ọ̀mọ̀wé yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n rí nípa ibi tí wọ́n ti ṣàwárí àwọn àkájọ náà fi hàn pé kí àwọn ará Bábílónì tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn ni wọ́n ti kọ wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lo ìlànà wíwo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ìgbàanì láti mọ déètì tí nǹkan ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àkájọ ìwé náà, tí wọ́n wo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn, bí ọ̀rọ̀ inú wọn ṣe tò tẹ̀ léra, àti bí àwọn lẹ́tà wọn ṣe rí, wọ́n rí i pé àkókò kan náà ni wọ́n kọ wọ́n, ìyẹn ìparí ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Níkẹyìn, wọ́n ṣàyẹ̀wò àkọtọ́ èdè, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń kọ èdè sílẹ̀, wọ́n wá sọ pé: “Àkọtọ́ èdè tí wọ́n lò nínú [àwọn àkájọ ìwé náà] bá àkókò táwọn awalẹ̀pìtàn sọ pé wọ́n kọ ọ́ mu, ó sì tún bá ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ayé ìgbà náà mu.”
Nígbà tí ìwé ìròyìn Bulletin of the American Schools of Oriental Research ń ṣàkópọ̀ ìwádìí àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n fi fàdákà ṣe náà, èyí tí wọ́n tún ń pè ní àkọsílẹ̀ Ketef Hinnom, ó ní: “A ò jayò pa tá a bá wá sọ pé òótọ́ lohun tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà gbọ́, ìyẹn ni pé nínú gbogbo ibi tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Bíbélì sí, [àkájọ ìwé wọ̀nyí] la tíì rí tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ.”
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Ihò ìsìnkú: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.; Ọ̀rọ̀ tó wà lára àkájọ ìwé: Fọ́tò © Israel Museum, Jerúsálẹ́mù; Àwọn aláṣẹ Israel Antiquities Authority ló yọ̀ǹda fọ́tò yìí