“Kí Ni Àmì Onígun Mẹ́ta Aláwọ̀ Àlùkò Náà Dúró Fún?”
NÍNÚ lẹ́tà tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ètò ìdájọ́ nílùú Seoul lórílẹ̀-èdè Kòríà kọ, ó sọ pé: “Ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, mo gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo kà á, mo rí àwọn ohun kan kọ́ nípa ìyà tí ìjọba Násì àti ti Kọ́múníìsì fi jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n mo ní ìbéèrè kan o. Nínú fọ́tò iwájú ìwé ìròyìn náà, mo rí àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò tí wọ́n dorí rẹ̀ kodò, tó wà lápá òsì aṣọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ni àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò náà dúró fún ná?”
Nígbà tí ìjọba Násì ń ṣàkóso nílẹ̀ Jámánì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bá wọn sọ pé “Heil Hitler” (Ti Hitler Ni Ìgbàlà), wọn ò sì dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí ogun. Èyí ló mú kí ìjọba Násì fojú wọn rí màbo, tí wọ́n sọ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlá lára wọn sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àti sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àwọn kan lára wọn sì pẹ́ níbẹ̀ gan-an. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì lára wọn ló kú, pípa ni wọ́n sì pa ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn.
Kí ni àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò tó wà lára aṣọ ẹ̀wọ̀n wọn dúró fún? Ìwé Anatomy of the SS State sọ pé: “Àmì àkànṣe wà lára aṣọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà láwọn àgọ́ [Násì] láti fi irú ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ hàn. Ṣáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀ làwọn aláṣẹ ti gbé ìlànà sísàmì sára aṣọ kalẹ̀. Wọ́n máa ń rán ìrépé aṣọ onígun mẹ́ta mọ́ aṣọ ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan, àwọ̀ ìrépé aṣọ náà ló sì máa fi irú ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ hàn. Àwọ̀ pupa dúró fún àwọn tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ òṣèlú, àwọ̀ àlùkò dúró fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọ̀ dúdú dúró fún àwọn tí ìwà wọn kò bá taráyé mu, àwọ̀ ewé dúró fún àwọn ọ̀daràn, àwọ̀ osùn dúró fún àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, àwọ̀ búlúù sì dúró fún àwọn tó sá kúrò nílùú. Yàtọ̀ sí àwọn àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ oríṣiríṣi yìí, wọ́n tún rán ìrépé aṣọ onígun mẹ́ta aláwọ̀ ìyeyè mọ́ àmì onígun mẹ́ta tó wà lára aṣọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ Júù kí àmì tiwọn lè dà bí ohun tí wọ́n ń pè ní Ìràwọ̀ Dáfídì tó ní igun mẹ́fà.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n John K. Roth sọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀ Holocaust Politics pé: “Ká láwọn èèyàn níbi gbogbo lè máa rántí ẹ̀kọ́ tí àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò kọ́ni ni, ìyẹn ni pé ó yẹ kéèyàn dúró lórí òtítọ́, ẹ̀kọ́ náà ì bá gbà wá lọ́wọ́ àjálù ọjọ́ iwájú, ì bá sì tọ́ wa sọ́nà ká lè máa hùwà ọmọlúwàbí tó máa múnú gbogbo èèyàn dùn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fídíò kan tí wọ́n pè ní Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dúró Gbọn-in Láìka Àtakò Gbígbóná Janjan Nazi Sí). Fídíò náà gbayì débi pé wọ́n gbẹ̀bùn lórí rẹ̀. O ò ṣe sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kó bá ọ ṣètò bí wàá ṣe wo fídíò yìí?