Wá Bá Wa Pé Jọ Lọ́jọ́ Wednesday, April 12
Alẹ́ Tó Yẹ Ká Rántí
Ní alẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù Kristi kú, ó fi ètò Ìrántí ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀. Ó lo wáìnì àti àkàrà aláìwú gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ ó sì pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Ó jẹ́ ayọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti pè ọ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ wa láti pa àṣẹ Jésù yìí mọ́, ká jọ ṣe Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Jọ̀wọ́ wo ẹ̀yìn ìwé pélébé yìí tàbí kó o bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ kó o lè mọ ibi tí a ó ti ṣe é, ọjọ́ tí a ó ṣe é, àti iye aago tó máa bẹ̀rẹ̀.