ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 4/1 ojú ìwé 32
  • Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 4/1 ojú ìwé 32

Ìkésíni . . .

Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà?

ÀJÁLÙ lóríṣiríṣi, àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí, ìwà ìbàjẹ́ láàárín àwọn èèyàn tó wà nípò gíga, àwọn akópayàbáni, ogun, ìwà ọ̀daràn. Bóyá la fi rí ọjọ́ kan téèyàn ò gbọ́ irú àwọn ìròyìn yìí. Yálà àwọn nǹkan wọ̀nyí kàn ọ́ tàbí wọn ò kàn ọ́, kò sọ́gbọ́n tó ò fi ní béèrè pé ibo ni ayé yìí ń lọ àti pé ǹjẹ́ a lè bọ́ nínú ìṣòro yìí?

Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà làwọn orílẹ̀-èdè tó ju igba [200] lọ káàkiri ayé yóò sọ àsọyé kan fún gbogbo ènìyàn, èyí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà?” Àsọyé náà yóò dá lórí ohun tí Ọlọ́run sọ àtohun tó ṣèlérí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí kò láṣìṣe kankan, nípa àwọn ìbéèrè ṣíṣe kókó wọ̀nyí:

Ǹjẹ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa ohun tó ń lọ nínú ayé?

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ fẹ́ràn aráyé?

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bìkítà nípa rẹ?

Níbi tó pọ̀ ju lọ, ọjọ́ Sunday, April 30, 2006 la ó sọ àsọyé náà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ ibi tí a ó ti sọ ọ́ àti àkókò tá a fẹ́ sọ ọ́.

A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ láti wá gbọ́ àsọyé tó ń fúnni níṣìírí tá a gbé ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí. Àsọyé náà yóò dáhùn ìbéèrè tó sọ pé: Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà? Ìdáhùn náà yóò sì tẹ́ ọ lọ́rùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́