ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 4/15 ojú ìwé 32
  • Ẹ̀tọ́ Láti Ní Orúkọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀tọ́ Láti Ní Orúkọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 4/15 ojú ìwé 32

Ẹ̀tọ́ Láti Ní Orúkọ

OLÚKÚLÙKÙ èèyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti ní orúkọ. Ní orílẹ̀-èdè Tahiti, kò sẹ́ni tí ò lórúkọ tó ń jẹ́, kódà ọmọ ọwọ́ tí wọ́n gbé sọ nù téèyàn ò mọ bàbá àti ìyá rẹ̀ pàápàá lórúkọ. Ilé iṣẹ́ ìjọba tí wọ́n máa ń tọ́jú àkọsílẹ̀ sí ló máa ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lórúkọ tí wọ́n á máa jẹ́ àti orúkọ míì tí yóò dúró fún orúkọ bàbá.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ẹnì kan wà tá a lè sọ pé àwọn èèyàn ti fi ẹ̀tọ́ yìí dù, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ gbogbo èèyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti ní orúkọ. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà ló jẹ́ pé “Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀,” làwọn èèyàn ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí! (Éfésù 3:14, 15) Ṣé ẹ rí i, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ lo orúkọ tí Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá ń jẹ́. Dípò ìyẹn, àwọn orúkọ oyè Ẹlẹ́dàá, irú bí “Ọlọ́run,” “Olúwa,” tàbí “Ẹni Ayérayé” ni wọ́n máa ń lò. Kí wá ni orúkọ rẹ̀ gan-an? Onísáàmù kan dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

Láàárín ọdún 1800 àti 1850 tí àwọn míṣọ́nnárì látinú Ẹgbẹ́ Àwọn Míṣọ́nnárì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá sí orílẹ̀-èdè Tahiti, oríṣiríṣi òrìṣà làwọn ará ilẹ̀ Polynesia ń bọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní orúkọ tiẹ̀, orúkọ àwọn tí wọ́n sì kà sí pàtàkì jù lọ nínú àwọn òrìṣà yìí ni Oro àti Taaroa. Àwọn míṣọ́nnárì yìí fẹ́ káwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run tó ni Bíbélì àtàwọn òrìṣà wọ̀nyẹn, ìdí nìyí tí wọ́n fi máa ń lo orúkọ Ọlọ́run níbi gbogbo. Bí wọ́n ṣe ń kọ orúkọ náà lédè Tahiti ni Iehova.

Ṣàṣà ibi làwọn èèyàn ò ti mọ orúkọ yẹn láyé ìgbà yẹn, wọ́n sì máa ń lò ó dáadáa nínú ọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́ àti nínú lẹ́tà tí wọ́n bá kọ. Ọba Pomare Kejì tó jẹ ní Tahiti ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún lo orúkọ náà dáadáa nínú lẹ́tà tó ń kọ sáwọn èèyàn. Ẹ̀rí pé ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú lẹ́tà rẹ̀ kan tó fi èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ, èyí táwọn èèyàn lè rí ní Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí Orílẹ̀-Èdè Tahiti Àtàwọn Erékùṣù Abẹ́ Rẹ̀. Fọ́tò lẹ́tà ọ̀hún lẹ̀ ń wò yìí. Èyí fi hàn pé àwọn tó gbé láyé ìgbà yẹn máa ń lo orúkọ Ọlọ́run dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibi ni orúkọ náà ti fara hàn nínú Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Tahiti, èyí tí wọ́n parí iṣẹ́ lórí rẹ̀ lọ́dún 1835.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ọba Pomare Kejì

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Ọba àti lẹ́tà: Collection du Musée de Tahiti et de ses Îles, Punaauia, Tahiti

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́