Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Lè Wọ Ọmọ Kékeré Lọ́kàn
ǸJẸ́ o ti rí ọmọdé kan tó ń ṣe bí ẹni tó ń jagun rí, tí ohun tó ń ṣe yẹn sì ń bà ọ́ lọ́kàn jẹ́? Ibi gbogbo la ti máa ń ráwọn tó ń ṣerú eré bẹ́ẹ̀, kódà àwọn ọmọ tó kéré gan-an ń ṣe é, nítorí pé ìwà ipá ló pọ̀ jù lọ nínú eré ìnàjú táwọn èèyàn máa ń ṣe lónìí. Báwo lo ṣe lè ran ọmọdé kan lọ́wọ́ láti kó àwọn ohun ìṣeré tó jẹ mọ́ ogun jíjà dànù kó sì fi àwọn ohun ìṣeré tí kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ogun rọ́pò wọn? Arábìnrin Waltraud, tó ti pẹ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Áfíríkà wá ọ̀nà láti ran ọmọdékùnrin kan lọ́wọ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Tìtorí ogun ni Waltraud ṣe kúrò lórílẹ̀-èdè tó ń gbé tó sì ṣí lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn nílẹ̀ Áfíríkà. Ibẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyá ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo ìgbà tó bá lọ kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń rí ọmọ náà tó ń fi ìbọn oníke kékeré kan ṣeré, ohun ìṣeré kan ṣoṣo tó sì ní nìyẹn. Waltraud ò rí i kó kọjú ìbọn náà sí ẹnikẹ́ni rí o, àmọ́ gbogbo ìgbà ló máa ń ṣí ìbọn náà tá a tún pa á dé, tá a máa ṣe bí ẹni pé òun ń kó ọta sínú rẹ̀.
Waltraud sọ fún ọmọkùnrin náà pé: “Werner, ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi wá sórílẹ̀-èdè yín? Nítorí ogun ni. Mo sá kúrò lórílẹ̀-èdè tí mò ń gbé nítorí àwọn èèyàn búburú tí wọ́n ń yìnbọn sáwọn èèyàn. Ìbọn wọn sì dà bíi tìẹ yìí. Ǹjẹ́ o rò pé ó dáa kéèyàn máa yìnbọn?”
Werner dáhùn pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé: “Rárá o, kò dáa bẹ́ẹ̀.”
Waltraud wá sọ pé: “Òótọ́ lo sọ.” Ó tún bi í pé: “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi máa ń wá sọ́dọ̀ ìwọ àti màmá rẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Ìdí ni pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn ni.” Waltraud wá sọ fún Werner pé: “Tó o bá fún mi ni ìbọn rẹ yìí, màá sọ ọ́ sígbó, màá sì wá gbé mọ́tò ìṣeré tó lẹ́sẹ̀ mẹ́rin fún ẹ.” Màmá Werner fọwọ́ sí ohun tí Waltraud sọ yìí.
Bí Werner ṣe mú ìbọn náà fún Waltraud nìyẹn. Ọ̀sẹ̀ mẹ́rin gbáko ló fi dúró kí ohun ìṣeré mìíràn tó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Mọ́tò ìṣeré tí wọ́n fi igi ṣe ni ohun ìṣeré tuntun yìí. Inú rẹ̀ dùn gan-an, tẹ̀ríntẹ̀rín ló sì fi gbà á.
Ǹjẹ́ o máa ń wá àkókò láti bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀? Ṣé o sì máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ wọ́n lọ́kàn kí wọ́n lè kó àwọn ohun ìṣeré tó jọ nǹkan ogun dànù? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí ayé lò ń kọ́ wọn yẹn.