ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/15 ojú ìwé 32
  • Bí “Ohun Èlò Tí Ó Túbọ̀ Jẹ́ Aláìlera” Ti Ṣeyebíye Tó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí “Ohun Èlò Tí Ó Túbọ̀ Jẹ́ Aláìlera” Ti Ṣeyebíye Tó
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/15 ojú ìwé 32

Bí “Ohun Èlò Tí Ó Túbọ̀ Jẹ́ Aláìlera” Ti Ṣeyebíye Tó

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [aya yín] gbé . . . ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Pétérù 3:7) Ǹjẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé àwọn obìnrin jẹ́ “ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera” bu iyì wọn kù lọ́nàkọnà? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí òǹkọ̀wé tí Ọlọ́run mí sí yìí ní lọ́kàn nígbà tó kọ àkọsílẹ̀ yìí.

Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pè ní “ọlá” lédè Gíríìkì túmọ̀ sí “ohun pàtàkì, ohun iyebíye . . . tàbí ohun téèyàn ń bọ̀wọ̀ fún.” Èyí fi hàn pé ńṣe ló yẹ kí Kristẹni ọkọ máa fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìgbatẹnirò bá aya rẹ̀ lò, kó kà á sí ohun èlò ẹlẹgẹ́, ohun tó ṣeyebíye gan-an. Èyí kò bù wọ́n kù rárá. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àtùpà àtayébáyé kan tí wọ́n ń pè ní àtùpà Tiffany. Kà sòótọ́, ohun ẹlẹgẹ́ ni àtùpà tó dára gan-an yìí. Ṣùgbọ́n o, ǹjẹ́ a lè wá sọ pé àtùpà yìí ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò torí pé ó jẹ́ ẹlẹgẹ́? Rárá o! Lọ́dún 1997, ó dín díẹ̀ ní mílíọ̀nù mẹ́ta owó dọ́là tí wọ́n ta ojúlówó àtùpà Tiffany níbi ọjà gbàǹjo kan! Dípò kí wọ́n máa fojú yẹpẹrẹ wo àtùpà yìí torí pé ó jẹ́ ẹlẹgẹ́, ńṣe ni jíjẹ́ tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ túbọ̀ mú kó ṣeyebíye sí i.

Lọ́nà kan náà, fífi ọlá fún obìnrin gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera kò bu iyì wọn kù bẹ́ẹ̀ ni kò sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ. Bí ọkọ kan bá ń fi “ìmọ̀” bá aya rẹ̀ gbé, irú ọkọ bẹ́ẹ̀ yóò máa gba ti aya rẹ̀ rò, yóò mọ ibi tí agbára rẹ̀ mọ, yóò mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́, yóò sì mọ ojú tó fi ń wo nǹkan àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. Ọkọ tó mọ̀kẹ́ aya rẹ̀ yóò máa rántí pé ìwà òun àti aya òun ò dọ́gba. Á máa gba ti aya rẹ̀ rò “kí àdúrà [rẹ̀] má bàa ní ìdènà.” (1 Pétérù 3:7) Bí ọkọ kan kò bá ń gba ti aya rẹ̀ rò nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ obìnrin, èyí lè ṣe àkóbá fún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó dájú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò fojú yẹpẹrẹ wo àwọn obìnrin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bu iyì àti ọlá fún wọn.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

© Christie’s Images Limited 1997

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́